Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Marku 4:3 - Yoruba Bible

3 “Ẹ fi etí sílẹ̀! Ọkunrin kan jáde lọ láti fúnrúgbìn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 Ẹ fi eti silẹ; Wo o, afunrugbin kan jade lọ ifunrugbin;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 “Ẹ fi etí sílẹ̀! Ní ọjọ́ kan, afúnrúgbìn kan jáde lọ láti lọ fúnrúgbìn rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Marku 4:3
29 Iomraidhean Croise  

Ẹ wá, ẹ̀yin ọmọ, ẹ tẹ́tí sí mi, n óo kọ yín ní ìbẹ̀rù OLUWA.


Gbọ́, ìwọ ọmọbinrin, ronú kí o sì tẹ́tí sílẹ̀, gbàgbé àwọn eniyan rẹ ati ilé baba rẹ;


Nisinsinyii, ẹ fetí sílẹ̀, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ farabalẹ̀ gbọ́ nǹkan tí mò ń sọ.


“Nisinsinyii, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ fetí sí mi, ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ń rìn ní ọ̀nà mi.


Fún irúgbìn ní àárọ̀, má sì ṣe dáwọ́ dúró ní ìrọ̀lẹ́, nítorí o kò mọ èyí tí yóo dàgbà, bóyá ti òwúrọ̀ ni tabi ti ìrọ̀lẹ́, tabi àwọn mejeeji.


“Ẹ fetí sí mi, ẹ̀yin aláìgbọràn, ẹ̀yin tí ẹ jìnnà sí ìgbàlà.


“Ẹ tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin ará ilé Jakọbu, ati gbogbo ará ilé Israẹli tí ó ṣẹ́kù; ẹ̀yin tí mo pọ̀n láti ọjọ́ tí wọ́n ti bi yín, tí mo sì gbé láti inú oyún.


Ó tún pa òwe mìíràn fún wọn. Ó ní, “Bí ìjọba ọ̀run ti rí nìyí. Ó dàbí ọkunrin kan tí ó gbin irúgbìn rere sí oko rẹ̀.


Nígbà tí ọkà dàgbà, tí ó yọ ọmọ, èpò náà dàgbà.


Ó sọ ọpọlọpọ ọ̀rọ̀ fún wọn pẹlu òwe. Ó ní: “Ní ọjọ́ kan, afunrugbin kan jáde lọ láti fúnrúgbìn.


Afunrugbin fúnrúgbìn ọ̀rọ̀ ìròyìn ayọ̀.


Ó bá ń fi òwe kọ́ wọn ní ọpọlọpọ nǹkan. Ó wí fún wọn ninu ẹ̀kọ́ rẹ̀ pé:


Bí ẹnikẹ́ni bá ní etí láti fi gbọ́ràn, kí ó gbọ́.”


Bí ó ti ń fúnrúgbìn lọ, díẹ̀ bọ́ sí ẹ̀bá ọ̀nà, àwọn ẹyẹ bá wá, wọ́n ṣà á jẹ.


Lẹ́yìn náà Jesu ní, “Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ràn, kí ó gbọ́!”


Peteru wá dìde dúró pẹlu àwọn aposteli mọkanla, ó sọ̀rọ̀ sókè, ó ní, “Ẹ̀yin ará, ẹ̀yin Juu, ati gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Jerusalẹmu, ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yìí ye yín, kí ẹ fetí sí ọ̀rọ̀ mi.


Mose wí fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ fi ọkàn sí àwọn ìlànà ati òfin tí mò ń kọ yín yìí, kí ẹ máa tẹ̀lé wọn, kí ẹ lè wà láàyè, kí ẹ lè dé ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun àwọn baba yín ń mu yín lọ, kí ẹ sì lè gbà á.


Ẹ fi etí sílẹ̀, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́. Ọlọrun ti yan àwọn mẹ̀kúnnù ayé yìí láti jẹ́ ọlọ́rọ̀ ninu igbagbọ ati láti jogún ìjọba tí ó ti ṣe ìlérí fún àwọn tí ó fẹ́ràn rẹ̀.


“Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ. “Ẹni tí ó bá ṣẹgun kò ní kú ikú keji.


“Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.


“Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ. “Ẹni tí ó bá ṣẹgun ni n óo fún ní àṣẹ láti jẹ ninu èso igi ìyè tí ó wà ninu ọgbà Ọlọrun.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan