Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Marku 4:12 - Yoruba Bible

12 Kí wọn baà lè la ojú sílẹ̀ ṣugbọn kí wọn má ríran; kí wọn gbọ́ títí ṣugbọn kí òye má yé wọn; kí wọn má baà ronupiwada, kí á má baà dáríjì wọ́n.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

12 Nitori ni ríri ki nwọn ki o le ri, ki nwọn má si kiyesi; ati ni gbigbọ́ ki nwọn ki o le gbọ́, ki o má si yé wọn; ki nwọn ki o má ba yipada, ki a má ba dari jì wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

12 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé, “ ‘wọn yóò rí i, wọn yóò sì gbọ́, kì yóò yé wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò sì yípadà sí Ọlọ́run. Tàbí kí a dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì wọ́n!’ ”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Marku 4:12
18 Iomraidhean Croise  

Ẹ mú àwọn eniyan mi jáde, àwọn tí wọ́n ní ojú, ṣugbọn tí ojú wọn ti fọ́, wọ́n ní etí, ṣugbọn etí wọn ti di.


Wọn kò mọ nǹkan, bẹ́ẹ̀ ni òye kò yé wọn. Nǹkankan ti bò wọ́n lójú kí wọn má baà lè ríran; ó sì ti sé wọn lọ́kàn kí òye má baà yé wọn.


Bóyá bí àwọn ará Juda bá gbọ́ nípa ibi tí mò ń gbèrò láti ṣe sí wọn, olukuluku lè yipada kúrò ninu ọ̀nà ibi rẹ̀, kí n lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ ati àìdára wọn jì wọ́n.”


Ẹ wá gbọ́, ẹ̀yin òmùgọ̀, aláìlọ́gbọ́n, ẹ̀yin tí ẹ lójú, ṣugbọn tí ẹ kò ríran; ẹ létí, ṣugbọn tí ẹ kò gbọ́ràn.


“Ìwọ ọmọ eniyan, ààrin àwọn olóríkunkun ni o wà: àwọn tí wọ́n ní ojú, ṣugbọn tí wọn kò fi ríran. Wọ́n ní etí, ṣugbọn wọn kò fi gbọ́ràn, nítorí pé ọmọ ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n.


Ẹ ní ojú lásán ni, ẹ kò ríran? Ẹ ní etí lásán ni, ẹ kò fi gbọ́ràn?


Ó ní, “Ẹ̀yin ni a fi fún láti mọ àṣírí ìjọba Ọlọrun, ṣugbọn fún àwọn yòókù, bí òwe bí òwe ni, pé wọn yóo máa wo nǹkan ṣugbọn wọn kò ní mọ ohun tí wọn rí, wọn yóo máa gbọ́ràn ṣugbọn òye ohun tí wọn gbọ́ kò ní yé wọn.


Nítorí náà, ẹ ronupiwada, kí ẹ yipada sọ́dọ̀ Ọlọrun bí ẹ bá fẹ́ kí á pa ẹ̀ṣẹ̀ yín rẹ́.


Ṣugbọn títí di òní yìí, OLUWA kò tíì jẹ́ kí òye ye yín, ojú yín kò ríran, bẹ́ẹ̀ ni etí yín kò gbọ́ràn.


Kí ó fi ìfarabalẹ̀ bá àwọn tí ó bá lòdì sí i wí, bóyá Ọlọrun lè fún wọn ní ọkàn ìrònúpìwàdà, kí wọ́n lè ní ìmọ̀ òtítọ́,


tí wọ́n bá wá yipada kúrò ninu ìsìn igbagbọ, kò sí ohun tí a lè ṣe tí wọ́n fi lè tún ronupiwada mọ́, nítorí wọ́n ti tún fi ọwọ́ ara wọn kan Ọmọ Ọlọrun mọ́ agbelebu, wọ́n sọ ikú rẹ̀ di nǹkan àwàdà.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan