Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Marku 4:11 - Yoruba Bible

11 Ó bá sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni a fi fún láti mọ ohun ìjìnlẹ̀ ìjọba Ọlọrun, ṣugbọn bí òwe bí òwe ni fún àwọn ẹlòmíràn tí ó wà lóde.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

11 O si wi fun wọn pe, Ẹnyin li a fifun lati mọ̀ ohun ijinlẹ ijọba Ọlọrun: ṣugbọn fun awọn ti o wà lode, gbogbo ohun wọnyi li a nfi owe sọ fun wọn:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

11 Ó sì dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin ni a gbà láààyè láti mọ ohun ìjìnlẹ̀ nípa ìjọba Ọlọ́run. Èyí tí ó pamọ́ sí àwọn tí ó wà lẹ́yìn agbo ìjọba náà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Marku 4:11
20 Iomraidhean Croise  

Nígbà náà ni Jesu sọ báyìí pé, “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Baba, Oluwa ọ̀run ati ayé, nítorí o ti pa nǹkan wọnyi mọ́ fún àwọn ọlọ́gbọ́n ati àwọn olóye, ṣugbọn o fi wọ́n han àwọn òpè.


Ó ní, “Ẹ̀yin ni a fi fún láti mọ àṣírí ìjọba Ọlọrun, ṣugbọn fún àwọn yòókù, bí òwe bí òwe ni, pé wọn yóo máa wo nǹkan ṣugbọn wọn kò ní mọ ohun tí wọn rí, wọn yóo máa gbọ́ràn ṣugbọn òye ohun tí wọn gbọ́ kò ní yé wọn.


A tún mọ̀ pé Ọmọ Ọlọrun ti dé, ó ti fún wa ní làákàyè kí á lè mọ ẹni Òtítọ́. À ń gbé inú Ọlọrun, àní inú Ọmọ rẹ̀, Jesu Kristi. Òun ni Ọlọrun tòótọ́ ati ìyè ainipẹkun.


Ẹ máa rìn bí ó ti yẹ láàrin àwọn alaigbagbọ, kí ó má sí pé ẹ nílò ati gba ohunkohun lọ́wọ́ wọn.


Ẹ máa gbé ìgbé-ayé yín pẹlu ọgbọ́n níwájú àwọn alaigbagbọ. Ẹ má ṣe jẹ́ kí àkókò kan kọjá láìjẹ́ pé ẹ lò ó bí ó ti yẹ.


Ṣugbọn kí ó jẹ́ ẹni tí ó ní ẹ̀rí rere lọ́dọ̀ àwọn tí kì í ṣe onigbagbọ, kí ó má baà bọ̀ sinu ẹ̀gàn, kí tàkúté Satani má baà mú un.


Ó jẹ́ kí á mọ àṣírí ìfẹ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ètò tí ó kún fún oore-ọ̀fẹ́ tí ó ti ṣe ninu Kristi.


Nítorí Ọlọrun tí ó ní kí ìmọ́lẹ̀ tàn láti inú òkùnkùn, òun ni ó tan ìmọ́lẹ̀ sí ọkàn wa, kí ìmọ́lẹ̀ ìmọ̀ ògo Ọlọrun lè tàn sí wa ní ojú Kristi.


Jesu sọ fún un pé, “O káre, Simoni, ọmọ Jona, nítorí kì í ṣe eniyan ni ó fi èyí hàn ọ́ bíkòṣe Baba mi tí ń bẹ lọ́run.


“Ṣugbọn ẹ̀yin ṣe oríire tí ojú yín ríran, tí etí yín sì gbọ́ràn.


Ta ni ó gbe yín ga ju ẹlòmíràn lọ? Kí ni ohun tí ẹ dá ní, tí kò jẹ́ pé ọwọ́ Ọlọrun ni ẹ ti rí i gbà? Kí wá ni ìdí ìgbéraga yín bí ẹni pé ẹ̀yin ni ẹ dá a ní?


Jesu wá pè wọ́n sọ́dọ̀, ó fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀ pé, “Báwo ni Satani ti ṣe lè lé Satani jáde?


Ó bá ń fi òwe kọ́ wọn ní ọpọlọpọ nǹkan. Ó wí fún wọn ninu ẹ̀kọ́ rẹ̀ pé:


Nígbà tí ó ku òun nìkan, àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀ ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila bèèrè ìtumọ̀ àwọn òwe tí ó fi ń sọ̀rọ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan