Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Marku 3:9 - Yoruba Bible

9 Ó bá sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọn tọ́jú ọkọ̀ ojú omi kan sí ìtòsí nítorí àwọn eniyan, kí wọn má baà fún un pa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

9 O si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, ki nwọn mu ọkọ̀ kekere kan sunmọ on, nitori ijọ enia, ki nwọn ki o má bà bilù u.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 Nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn, Jesu sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti ṣètò ọkọ̀ ojú omi kékeré kan sílẹ̀ fún un láti lọ, láti lé àwọn èrò sẹ́yìn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Marku 3:9
9 Iomraidhean Croise  

Lẹ́yìn tí Jesu ti tú àwọn eniyan ká, ó wọ inú ọkọ̀ ojú omi, ó bá lọ sí agbègbè Magadani.


Jesu tún bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ àwọn eniyan lẹ́bàá òkun. Ogunlọ́gọ̀ eniyan péjọ pọ̀ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi níláti bọ́ sin ọkọ̀ ojú omi kan, ó bá jókòó níbẹ̀ lójú omi. Gbogbo àwọn eniyan wà ní èbúté, wọ́n jókòó lórí iyanrìn.


Wọ́n bá fi àwọn eniyan sílẹ̀, wọ́n mú un lọ pẹlu wọn ninu ọkọ̀ tí ó wà. Àwọn ọkọ̀ mìíràn wà níbẹ̀ pẹlu.


Bí ó ti jáde kúrò ninu ọkọ̀, ọkunrin wèrè kan wá pàdé rẹ̀ láti inú ibojì pàlàpálá àpáta.


Lójú kan náà Jesu mọ̀ ninu ara rẹ̀ pé agbára ìwòsàn jáde lára òun. Ó bá yipada sí àwọn eniyan, ó bèèrè pé, “Ta ni fọwọ́ kàn mí láṣọ?”


Wọ́n bá bọ́ sinu ọkọ̀ ojú omi kan, wọ́n fẹ́ yọ́ lọ sí ibi tí kò sí eniyan.


Ní àkókò kan, bí Jesu ti dúró létí òkun Genesarẹti, ọ̀pọ̀ eniyan péjọ sọ́dọ̀ rẹ̀ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọrun.


Jesu bá wọ inú ọ̀kan ninu àwọn ọkọ̀ náà tí ó jẹ́ ti Simoni, ó ní kí wọ́n tù ú kúrò létí òkun díẹ̀. Ni ó bá jókòó ninu ọkọ̀, ó ń kọ́ àwọn eniyan.


Nígbà tí Jesu mọ̀ pé wọn ń fẹ́ wá fi ipá mú òun kí wọ́n sì fi òun jọba, ó yẹra kúrò níbẹ̀, òun nìkan tún pada lọ sórí òkè.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan