Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Marku 3:8 - Yoruba Bible

8 láti Idumea ati apá ìlà oòrùn odò Jọdani ati agbègbè Tire ati ti Sidoni. Ogunlọ́gọ̀ eniyan wọ́ lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ nígbà tí wọ́n gbọ́ ohun tí ó ń ṣe.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

8 Ati lati Jerusalemu, ati lati Idumea, ati lati oke odò Jordani, ati awọn ti o wà niha Tire on Sidoni, ijọ enia pipọ; nigbati nwọn gbọ́ ohun nla ti o ṣe, nwọn tọ̀ ọ wá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 Nígbà tí wọ́n gbọ́ ìròyìn iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe, ọ̀pọ̀ ènìyàn sì tọ̀ ọ́ wá láti Judea, Jerusalẹmu àti Idumea, àti láti apá kejì odò Jordani àti láti ìhà Tire àti Sidoni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Marku 3:8
18 Iomraidhean Croise  

Àwọn ará Tire yóo máa fi ẹ̀bùn wá ojurere rẹ, àní, àwọn eniyan tí wọ́n ní ọrọ̀ jùlọ.


Tí mo bá ń ka àwọn ilẹ̀ tí ó mọ rírì mi, n óo dárúkọ Ijipti ati Babiloni, Filistia ati Tire, ati Etiopia. Wọn á máa wí pé, “Ní Jerusalẹmu ni wọ́n ti bí eléyìí.”


Nítorí mo ti rẹkẹ idà mi lókè ọ̀run, yóo sọ̀kalẹ̀ láti ṣe ìdájọ́ àwọn ará Edomu; yóo sọ̀kalẹ̀ sórí àwọn tí mo fẹ́ parun.


bí o ti yọ ilẹ̀ Israẹli nígbà tí ilé wọn di ahoro. Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe sí ọ, ìwọ náà óo di ahoro. Gbogbo òkè Seiri ati gbogbo ilẹ̀ Edomu yóo di ahoro. Ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.”


“N óo fi ìtara sọ̀rọ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù ati gbogbo Edomu, tí wọ́n fi tayọ̀tayọ̀ pẹlu ọkàn ìkórìíra sọ ilẹ̀ mi di ogún wọn, kí wọ́n lè gbà á, kí wọ́n sì pín in mọ́wọ́, nítorí wọ́n rò pé ilẹ̀ mi ti di tiwọn.


Ó ní, “O gbé! Korasini. Ìwọ náà sì gbé! Bẹtisaida. Nítorí bí ó bá jẹ́ pé ní Tire ati ní Sidoni ni a ti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tí a ṣe láàrin yín ni, wọn ìbá ti ronupiwada tipẹ́tipẹ́, tàwọn ti aṣọ ọ̀fọ̀ lára ati eérú lórí.


Ọpọlọpọ eniyan ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn láti Galili ati Ìlú Mẹ́wàá ati Jerusalẹmu ati Judia, ati láti òdìkejì Jọdani.


Láti ibẹ̀ Jesu gbéra, ó lọ sí agbègbè ìlú Tire, ó sì wọ̀ sí ilé kan. Kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀, ṣugbọn kò lè fi ara pamọ́.


Ó tún jáde kúrò ní agbègbè ìlú Tire, ó la ìlú Sidoni kọjá lọ sí òkun Galili ní ọ̀nà ààrin Ìlú Mẹ́wàá.


Nígbà tí Jesu sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè pẹlu wọn, ó dúró ní ibi tí ilẹ̀ gbé tẹ́jú. Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ati ọ̀pọ̀ àwọn eniyan láti gbogbo Judia ati Jerusalẹmu ati Tire ati Sidoni, ní agbègbè ẹ̀bá òkun.


Àpèjúwe ìpín tí ó kan ẹ̀yà Juda lára ilẹ̀ tí àwọn ọmọ Israẹli gbà, tí a pín fún wọn gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn nìyí: Ilẹ̀ náà lọ títí dé apá ìhà gúsù, ní ààlà ilẹ̀ Edomu, títí dé aṣálẹ̀ Sini.


àwọn ìlú tí ó jẹ́ tiwọn ní ìpẹ̀kun apá ìhà gúsù lẹ́bàá ààlà Edomu nìwọ̀nyí: Kabiseeli, Ederi, Jaguri,


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan