Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Marku 3:5 - Yoruba Bible

5 Jesu wò yíká pẹlu ibinu, inú rẹ̀ sì bàjẹ́ nítorí pé ọkàn wọn le. Ó wá wí fún ọkunrin náà pé, “Na ọwọ́ rẹ.” Ó bá nà án. Ọwọ́ rẹ̀ sì bọ́ sípò.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

5 Nigbati o si fi ibinu wò gbogbo wọn yiká, ti inu rẹ̀ bajẹ nitori lile àiya wọn, o wi fun ọkunrin na pe, Nà ọwọ́ rẹ. O si nà a: ọwọ́ rẹ̀ si pada bọ̀ sipò gẹgẹ bi ekeji.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 Nígbà tí ó sì wo gbogbo wọn yíká pẹ̀lú ìbínú, ọkàn rẹ̀ sì bàjẹ́ nítorí líle àyà wọn, ó sọ fún ọkùnrin náà pé, “Na ọwọ́ rẹ jáde.” Ó nà án jáde, ọwọ́ náà sì bọ̀ sípò padà pátápátá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Marku 3:5
29 Iomraidhean Croise  

inú rẹ̀ bàjẹ́ gidigidi pé ó dá eniyan sí ayé, ó sì dùn ún,


Jeroboamu ọba bẹ wolii náà pé, “Jọ̀wọ́, bẹ OLUWA Ọlọrun rẹ, kí o sì gbadura sí i pé kí ó wo apá mi sàn.” Wolii náà bá gbadura sí OLUWA, apá Jeroboamu ọba sì sàn, ó pada sí bí ó ti wà tẹ́lẹ̀.


Inú bí mi gan-an, mo bá fọ́n gbogbo ẹrù Tobaya jáde kúrò ninu yàrá náà.


Fún ogoji ọdún gbáko ni ọ̀rọ̀ wọn fi sú mi, tí mo sọ pé, “Ọkàn àwọn eniyan wọnyi ti yapa, wọn kò sì bìkítà fún ìlànà mi.”


Ó bá sọ fún ọkunrin náà pé, “Na ọwọ́ rẹ.” Ó bá nà án. Ọwọ́ rẹ̀ bá bọ́ sípò gẹ́gẹ́ bí ekeji.


Jesu bá bi wọ́n léèrè pé, “Èwo ni ó dára: láti ṣe ìrànlọ́wọ́ ni tabi láti ṣe ìbàjẹ́ ní Ọjọ́ Ìsinmi? Láti gba ẹ̀mí là ni tabi láti pa ẹ̀mí run?” Ṣugbọn wọn kò fọhùn.


Ṣugbọn Oluwa dá a lóhùn pé, “Ẹ̀yin alágàbàgebè! Èwo ninu yín ni kì í tú mààlúù tabi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ ní ibùjẹ ẹran kí ó lọ fún un ní omi ní Ọjọ́ Ìsinmi?


Nígbà tí ó rí wọn, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ lọ fi ara yín hàn alufaa.” Bí wọ́n ti ń lọ, ara wọn bá dá.


Ó wá wo gbogbo wọn yíká, ó sọ fún ọkunrin náà pé, “Na ọwọ́ rẹ.” Ó ṣe bẹ́ẹ̀. Ọwọ́ rẹ̀ bá bọ́ sípò.


Ó wí fún un pé, “Lọ bọ́jú ninu adágún tí ó ń jẹ́ Siloamu.” (Ìtumọ̀ Siloamu ni “rán níṣẹ́.”) Ọkunrin náà lọ, ó bọ́jú, ó bá ríran.


Ará, mo fẹ́ kí ẹ mọ ohun àṣírí yìí, kí ẹ má baà ro ara yín jù bí ó ti yẹ lọ. Òun ni pé, apá kan ninu àwọn ọmọ Israẹli yóo jẹ́ alágídí ọkàn títí di ìgbà tí iye àwọn tí a yàn láti àwọn orílẹ̀-èdè yòókù yóo fi dé ọ̀dọ̀ Ọlọrun lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́.


Ṣugbọn ọkàn wọn ti le, nítorí títí di ọjọ́ òní, aṣọ náà ni ó ń bo ọkàn wọn nígbà tí wọn bá ń ka ìwé majẹmu àtijọ́. Wọn kò mú aṣọ náà kúrò, nítorí nípasẹ̀ Kristi ni majẹmu àtijọ́ fi di asán.


Ọkàn àwọn yìí ti ṣókùnkùn, ó sì ti yàtọ̀ pupọ sí irú ìgbé-ayé tí Ọlọrun fẹ́. Nítorí òpè ni wọ́n, ọkàn wọn ti le.


Bí ẹ bá bínú, ẹ má jẹ́ kí ibinu mu yín dẹ́ṣẹ̀. Ẹ má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ ba yín ninu ibinu.


Ẹ má kó ìbànújẹ́ bá Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọrun, tí Ọlọrun fi ṣèdìdì yín títí di ọjọ́ ìràpadà.


Nítorí náà, mo bínú sí ìran wọn. Mo ní, ‘Nígbà gbogbo ni wọ́n máa ń ṣìnà ní ọkàn wọn. Iṣẹ́ mi kò yé wọn.’


Àwọn ta ni Ọlọrun bínú sí ní ogoji ọdún? Ṣebí àwọn tí ó ṣẹ̀ ni, tí òkú wọn wà káàkiri ní aṣálẹ̀.


Nígbà tí a ti ṣe é ní àṣepé, ó wá di orísun ìgbàlà tí kò lópin fún gbogbo àwọn tí wọ́n bá gbà á gbọ́.


Wọ́n ń sọ fún àwọn òkè ati àpáta pé, “Ẹ wó lù wá, kí ẹ pa wá mọ́ kúrò lójú ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ ati ibinu Ọ̀dọ́ Aguntan.


Wọ́n bá kó gbogbo àwọn àjèjì oriṣa tí ó wà lọ́wọ́ wọn dànù, wọ́n sì ń sin OLUWA. Inú bí OLUWA, nítorí ìpọ́njú àwọn ọmọ Israẹli.


Jonatani sì fi ibinu dìde kúrò ní ìdí tabili oúnjẹ, kò sì jẹun ní ọjọ́ náà, tíí ṣe ọjọ́ keji oṣù. Inú rẹ̀ bàjẹ́ gidigidi fún Dafidi, nítorí pé baba rẹ̀ dójú tì í.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan