Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Marku 2:8 - Yoruba Bible

8 Ṣugbọn Jesu mọ̀ ninu ara rẹ̀ pé wọ́n ń ro èrò báyìí ninu ọkàn wọn. Ó wí fún wọn pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń kùn sinu?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

8 Lojukanna bi Jesu ti woye li ọkàn rẹ̀ pe, nwọn ngbèro bẹ̃ ninu ara wọn, o wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi nrò nkan wọnyi ninu ọkàn nyin?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 Lójúkan náà bí Jesu tí wòye nínú ọkàn rẹ̀ pé wọn ń gbèrò bẹ́ẹ̀ ní àárín ara wọn, ó wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yìn fi ń ro nǹkan wọ̀nyí nínú ọkàn yín?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Marku 2:8
23 Iomraidhean Croise  

Ọlọrun mi, mo mọ̀ pé ò máa yẹ ọkàn wò, o sì ní inú dídùn sí òtítọ́; tọkàntọkàn mi ni mo fi mú gbogbo nǹkan wọnyi wá fún ọ, mo sì ti rí i bí àwọn eniyan rẹ ti fi tọkàntọkàn ati inú dídùn mú ọrẹ wọn wá fún ọ.


O mọ ìgbà tí mo jókòó, ati ìgbà tí mo dìde; o mọ èrò ọkàn mi láti òkèèrè réré.


Ohun ìríra ni èrò ọkàn ẹni ibi lójú OLUWA, ṣugbọn ọrọ̀ àwọn ẹni mímọ́ jẹ́ dídùn inú rẹ̀.


Ẹ̀ṣẹ̀ ni ète òmùgọ̀, ẹni ìríra sì ni pẹ̀gànpẹ̀gàn.


Kí eniyan burúkú fi ọ̀nà ibi rẹ̀ sílẹ̀, kí alaiṣododo kọ èrò burúkú rẹ̀ sílẹ̀, kí ó yipada sí OLUWA, kí OLUWA lè ṣàánú rẹ̀. Kí ó yipada sọ́dọ̀ Ọlọrun wa, nítorí Ọlọrun yóo dáríjì í lọpọlọpọ.


OLUWA Ọlọrun ní, “Ní ọjọ́ náà èròkerò yóo wá sí ọkàn rẹ,


Nígbà tí Jesu mọ̀ bẹ́ẹ̀, ó bá kúrò níbẹ̀. Ọpọlọpọ eniyan sì tẹ̀lé e, ó sì wo gbogbo wọn sàn.


Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí wí láàrin ara wọn pé, “Nítorí a kò mú oúnjẹ lọ́wọ́ wá ni ó ṣe sọ bẹ́ẹ̀.”


Ṣugbọn Jesu mọ èrò inú wọn; ó bá bi wọ́n pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń ro èrò burúkú ninu ọkàn yín?


“Kí ló dé tí eléyìí fi ń sọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀? Ó ń sọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ọlọrun. Ta ni lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji ni bíkòṣe Ọlọrun nìkan?”


Èwo ni ó rọrùn jù: Láti wí fún arọ náà pé, ‘A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́,’ tabi láti wí pé, ‘Dìde, gbé ibùsùn rẹ, kí o máa rìn?’


Nítorí láti inú ọkàn eniyan ni ète burúkú ti ń jáde: ìṣekúṣe, olè jíjà, ìpànìyàn,


Ṣugbọn ó ní, “Kí ni ń bà yín lẹ́rù. Kí ni ó ń mú iyè meji wá sí ọkàn yín?


Jesu ti mọ ohun tí wọ́n ń bá ara wọn sọ, ó bá dá wọn lóhùn pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń ro irú èrò báyìí ní ọkàn yín?


Ṣugbọn ó ti mọ ohun tí wọn ń rò ní ọkàn wọn. Ó sọ fún ọkunrin náà tí ọwọ́ rẹ̀ rọ pé, “Dìde kí o dúró ní ààrin.” Ọkunrin náà bá dìde dúró.


Jesu tún bi í ní ẹẹkẹta pé, “Simoni ọmọ Johanu, ǹjẹ́ o fẹ́ràn mi?” Ó dun Peteru nítorí Jesu bi í ní ẹẹkẹta pé, “Ǹjẹ́ o fẹ́ràn mi?” Ó wá sọ fún Jesu pé, “Oluwa, o mọ ohun gbogbo, o mọ̀ pé mo fẹ́ràn rẹ.” Jesu sọ fún un pé, “Máa bọ́ àwọn aguntan mi.


Ṣugbọn àwọn tí kò gbàgbọ́ wà ninu yín.” Jesu sọ èyí nítorí láti ìbẹ̀rẹ̀ ni ó ti mọ àwọn tí kò gbàgbọ́ ati ẹni tí yóo fi òun lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́.


Peteru bá bi í pé, “Anania, kí ló dé tí Satani fi gbà ọ́ lọ́kàn tí o fi ṣe èké sí Ẹ̀mí Mímọ́, tí o fi yọ sílẹ̀ ninu owó tí o rí lórí ilẹ̀ náà?


Nítorí náà, ronupiwada kúrò ninu ohun burúkú yìí, kí o tún bẹ Oluwa kí ó dárí èrò ọkàn rẹ yìí jì ọ́.


Kò sí ẹ̀dá kan tí ó lè fara pamọ́ níwájú rẹ̀. Gbogbo nǹkan ṣípayá kedere níwájú Ọlọrun, ẹni tí a óo jíyìn iṣẹ́ wa fún.


N óo fi ikú pa àwọn ọmọ rẹ̀. Gbogbo àwọn ìjọ ni yóo wá mọ̀ pé Èmi ni Èmi máa ń wádìí ọkàn ati èrò ẹ̀dá, n óo sì fi èrè fún olukuluku yín gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan