Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Marku 2:7 - Yoruba Bible

7 “Kí ló dé tí eléyìí fi ń sọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀? Ó ń sọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ọlọrun. Ta ni lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji ni bíkòṣe Ọlọrun nìkan?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

7 Ẽṣe ti ọkunrin yi fi sọrọ bayi? o nsọ ọrọ-odi; tali o le dari eṣẹ jìni bikoṣe ẹnikan, aní Ọlọrun?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 “Èéṣe ti ọkùnrin yìí fi sọ̀rọ̀ báyìí? Ó ń sọ̀rọ̀-òdì. Ta ni ó lè darí ẹ̀ṣẹ̀ ji ni bí ko ṣe Ọlọ́run nìkan?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Marku 2:7
15 Iomraidhean Croise  

Ta ló lè mú ohun mímọ́ jáde láti inú ohun tí kò mọ́? Kò sí ẹni náà.


Ṣugbọn ní ìkáwọ́ rẹ ni ìdáríjì wà, kí á lè máa bẹ̀rù rẹ.


Èmi, èmi ni mo pa ẹ̀ṣẹ̀ yín rẹ́, nítorí ti ara mi; n kò sì ní ranti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín mọ́.


Aláàánú ni ọ́ OLUWA Ọlọrun wa, ò sì máa dáríjì ni, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti ṣọ̀tẹ̀ sí ọ.


Ta ló dàbí rẹ, Ọlọrun, tí ó ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji eniyan, tí ó sì ń fojú fo ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan ìní rẹ̀ yòókù, ibinu rẹ kì í wà títí lae, nítorí pé a máa dùn mọ́ ọ láti fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn.


Olórí Alufaa bá fa aṣọ rẹ̀ ya, ó ní, “O sọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ọlọrun. Ẹlẹ́rìí wo ni a tún ń wá? Ẹ ti gbọ́ ọ̀rọ̀ àfojúdi tí ó sọ sí Ọlọrun nisinsinyii.


Àwọn amòfin kan ń rò ninu ara wọn pé, “Ọkunrin yìí ń sọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ọlọrun.”


Ẹ ti gbọ́ tí ó sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọrun! Kí ni ẹ wí?” Gbogbo wọn bá dá a lẹ́bi, wọ́n ní ikú ni ó tọ́ sí i.


Ṣugbọn àwọn amòfin kan jókòó níbẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kùn sinu pé,


Ṣugbọn Jesu mọ̀ ninu ara rẹ̀ pé wọ́n ń ro èrò báyìí ninu ọkàn wọn. Ó wí fún wọn pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń kùn sinu?


Àwọn amòfin ati àwọn Farisi bẹ̀rẹ̀ sí bá ara wọn sọ pé, “Ta ni eléyìí tí ó ń sọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ọlọrun báyìí? Ta ni lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji eniyan lẹ́yìn Ọlọrun nìkan ṣoṣo?”


Àwọn tí wọ́n jọ ń jẹun bà bẹ̀rẹ̀ sí sọ láàrin ara wọn pé, “Ta ni eléyìí tí ó ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji eniyan?”


Àwọn Juu dá a lóhùn pé, “Kì í ṣe nítorí iṣẹ́ rere ni a fi fẹ́ sọ ọ́ ní òkúta, nítorí ọ̀rọ̀ àfojúdi tí o sọ sí Ọlọrun ni; nítorí pé ìwọ tí ó jẹ́ eniyan sọ ara rẹ di Ọlọrun.”


kí ló dé tí ẹ fi sọ pé mò ń sọ ọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ọlọrun nítorí mo wí pé, ‘Ọmọ Ọlọrun ni mí,’ èmi tí Baba yà sọ́tọ̀, tí ó rán wá sí ayé?


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan