Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Marku 2:4 - Yoruba Bible

4 Nígbà tí wọn kò lè gbé e dé ọ̀dọ̀ rẹ̀ nítorí ọ̀pọ̀ eniyan, wọ́n dá òrùlé lu ní ọ̀kánkán ibi tí Jesu wà. Nígbà tí wọ́n ti dá a lu tán, wọ́n sọ ọkunrin arọ náà kalẹ̀ ti òun ti ibùsùn rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

4 Nigbati nwọn kò si le sunmọ ọ nitori ọ̀pọ enia, nwọn si ṣí orule ile nibiti o gbé wà: nigbati nwọn si da a lu tan, nwọn sọ akete na kalẹ lori eyiti ẹlẹgba na dubulẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Nígbà tí wọn kò sì le dé ọ̀dọ̀ Jesu, nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn, wọ́n dá òrùlé ilé lu ní ọ̀gangan ibi tí Jesu wà. Wọ́n sì sọ ọkùnrin arọ náà kalẹ̀ ti òun ti àkéte rẹ̀ níwájú Jesu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Marku 2:4
3 Iomraidhean Croise  

Òkìkí rẹ̀ kàn ká gbogbo Siria. Àwọn eniyan ń gbé gbogbo àwọn tí ó ní oríṣìíríṣìí àrùn ati àìlera wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ati àwọn tí ẹ̀mí Èṣù ń dà láàmú, ati àwọn tí wárápá mú ati àwọn arọ; ó sì ń wò wọ́n sàn.


Nígbà tí wọn kò rí ọ̀nà gbé e dé ọ̀dọ̀ rẹ̀ nítorí ọ̀pọ̀ eniyan, wọ́n gbé e gun orí òrùlé. Wọ́n bá dá òrùlé lu kí wọ́n fi lè gbé arọ náà pẹlu ibùsùn rẹ̀ sí ààrin àwọn eniyan níwájú Jesu.


“Tí ẹ bá kọ́ ilé titun, ẹ níláti ṣe ìgbátí sí òrùlé rẹ̀ yípo, kí ẹ má baà wá di ẹlẹ́bi bí ẹnikẹ́ni bá jábọ́ láti orí òrùlé yín, tí ó sì kú.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan