Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Marku 13:2 - Yoruba Bible

2 Jesu wí fún un pé, “O rí ilé yìí bí ó ti tóbi tó? Kò ní sí òkúta kan lórí ekeji níhìn-ín tí a kò ní wó lulẹ̀.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

2 Jesu si dahùn wi fun u pe, Iwọ ri ile nla wọnyi? Kì yio si okuta kan ti a o fi silẹ lori ekeji, ti a kì yio wó lulẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Jesu dáhùn pé, “Ìwọ rí ilé ńlá wọ̀nyí? Kì yóò sí òkúta kan tí a ó fi sílẹ̀ lórí èkejì tí a kì yóò wó lulẹ̀.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Marku 13:2
10 Iomraidhean Croise  

“Ní ìgbà Hesekaya ọba Juda, Mika ará Moreṣeti sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún gbogbo àwọn ará Juda pé OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, ‘A óo kọ Sioni bí ilẹ̀ oko, Jerusalẹmu yóo di òkítì àlàpà; òkè ilé yìí yóo sì di igbó kìjikìji.’


Lẹ́yìn ọdún mejilelọgọta lọ́nà meje yìí, wọn óo pa ẹni àmì òróró Ọlọrun kan láìṣẹ̀. Àwọn ọmọ ogun alágbára kan tí yóo joyè, yóo pa Jerusalẹmu ati Tẹmpili run. Òpin óo dé bá a bí àgbàrá òjò, ogun ati ìsọdahoro tí a ti fi àṣẹ sí yóo dé.


Nítorí náà, nítorí yín, a óo ro Sioni bí oko, Jerusalẹmu yóo di àlàpà, ahoro tẹmpili yóo sì di igbó kìjikìji.


Ó sọ fún wọn pé, “Ṣé ẹ rí gbogbo ilé yìí, mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé kò ní ku òkúta kan lórí ekeji tí wọn kò ní wó palẹ̀.”


“Ẹ rí gbogbo nǹkan wọnyi, ọjọ́ ń bọ̀ nígbà tí kò ní sí òkúta kan lórí ekeji tí a kò ní wó lulẹ̀.”


Nítorí a gbọ́ nígbà tí ó sọ pé Jesu ti Nasarẹti yóo wó ilé yìí, yóo yí àwọn àṣà tí Mose fún wa pada.”


Má wulẹ̀ wọn àgbàlá Tẹmpili tí ó wà lóde, nítorí a ti fi fún àwọn alaigbagbọ. Wọn yóo gba ìlú mímọ́ fún oṣù mejilelogoji.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan