Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Marku 12:3 - Yoruba Bible

3 Ṣugbọn nínà ni wọ́n nà án, wọ́n bá lé e pada ní ọwọ́ òfo.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 Nwọn si mu u, nwọn lù u, nwọn si rán a pada lọwọ̀ ofo.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Ṣùgbọ́n àwọn àgbẹ̀ wọ̀n-ọn-nì lu ìránṣẹ́ ọkùnrin náà, wọ́n sì rán an padà lọ́wọ́ òfo.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Marku 12:3
29 Iomraidhean Croise  

Àbí o kò gbọ́ nígbà tí Jesebẹli ń pa àwọn wolii OLUWA, pé mo kó ọgọrun-un ninu wọn pamọ́ sinu ihò àpáta meji, mo kó araadọta sinu ihò kọ̀ọ̀kan, mo sì ń fún wọn ní oúnjẹ ati omi.


Nígbà tí Jesebẹli bẹ̀rẹ̀ sí pa àwọn wolii OLUWA, Ọbadaya yìí ló kó ọgọrun-un ninu wọn pamọ́ sinu ihò àpáta meji, ó kó aadọta sinu ihò kọ̀ọ̀kan, ó sì ń fún wọn ní oúnjẹ ati omi.


Elija dáhùn pé, “Mò ń jowú nítorí ìwọ OLUWA, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun nítorí pé àwọn ọmọ Israẹli ti kọ majẹmu rẹ tì, wọ́n ti wó pẹpẹ rẹ lulẹ̀, wọ́n sì ti fi idà pa àwọn wolii rẹ. Èmi nìkan ṣoṣo ni mo ṣẹ́kù, wọ́n sì fẹ́ gba ẹ̀mí èmi náà.”


Ó bá dáhùn pé, “Mò ń jowú nítorí OLUWA, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, nítorí pé àwọn ọmọ Israẹli ti da majẹmu rẹ̀, wọ́n ti wó pẹpẹ rẹ̀ lulẹ̀, wọ́n sì ti fi idà pa àwọn wolii rẹ̀. Èmi nìkan ṣoṣo, ni mo ṣẹ́kù, wọ́n sì fẹ́ gba ẹ̀mí èmi náà.”


Ẹ ní, èmi ọba ni mo ní kí ẹ sọ fún wọn pé, kí wọ́n jù ú sinu ẹ̀wọ̀n, kí wọn sì máa fún un ní àkàrà lásán ati omi, títí tí n óo fi pada dé ní alaafia.”


Ọ̀rọ̀ yìí mú kí inú bí Asa sí wolii Hanani, ó sì kan ààbà mọ́ ọn lẹ́sẹ̀ ninu túbú, nítorí inú bí i sí i fún ohun tí ó sọ. Asa ọba fi ìyà jẹ àwọn kan ninu àwọn ará ìlú ní àkókò náà.


Ṣugbọn, yẹ̀yẹ́ ni wọ́n ń fi àwọn iranṣẹ Ọlọrun ṣe. Wọn kò náání ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n sì ń kẹ́gàn àwọn wolii rẹ̀ títí tí OLUWA fi bínú sí wọn, débi pé kò sí àtúnṣe.


“Ṣugbọn, wọ́n ṣe àìgbọràn, wọ́n sì ṣọ̀tẹ̀ sí ọ. Wọ́n pa àwọn òfin rẹ tì sí apákan, wọ́n pa àwọn wolii rẹ tí wọ́n ti ń kìlọ̀ fún wọn pé kí wọ́n yipada sí ọ, wọ́n sì ń hùwà àbùkù sí ọ.


Mo na àwọn ọmọ yín lásán ni, wọn kò gba ẹ̀kọ́. Ẹ̀yin gan-an ni ẹ fi idà pa àwọn wolii yín ní àparun, bíi kinniun tí ń pa ẹran kiri.


ó ní kí wọn lu Jeremaya, kí wọn kàn ààbà mọ́ ọn lẹ́sẹ̀ ní ẹnu ọ̀nà Bẹnjamini ti òkè, ní ilé OLUWA.


“Èmi OLUWA ti fi ìwọ Sefanaya jẹ alufaa dípò Jehoiada tí ó jẹ́ alufaa tẹ́lẹ̀ rí, ati pé mo ní kí o máa ṣe alabojuto gbogbo àwọn wèrè tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní ilé èmi OLUWA, kí o sì máa kan ààbà mọ́ wọn ní ẹsẹ̀, kí o máa fi okùn sí wọn lọ́rùn.


wọ́n ní, “A kò ní fetí sì ọ̀rọ̀ tí ò ń bá wa sọ lórúkọ OLUWA.


Obinrin Kenaani kan tí ó ń gbé ibẹ̀ bá jáde, ó ń kígbe pé, “Ṣàánú mi, Oluwa, ọmọ Dafidi. Ẹ̀mí èṣù ní ń da ọdọmọbinrin mi láàmú.”


Nígbà tí ó tó àkókò, ó rán ẹrú rẹ̀ kan lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn alágbàro náà pé, kí ó lọ gbà ninu èso àjàrà wá lọ́wọ́ wọn.


Ó tún rán ẹrú mìíràn lọ sí ọ̀dọ̀ wọn. Wọ́n lu òun lórí ní àlùbẹ́jẹ̀, wọ́n sì dójú tì í.


Èwo ninu àwọn wolii ni àwọn Baba yín kò ṣe inúnibíni sí? Wọ́n pa àwọn tí wọ́n sọtẹ́lẹ̀ pé Ẹni olódodo yóo dé. Ní àkókò yìí ẹ wá dìtẹ̀ sí i, ẹ ṣe ikú pa á.


Àwọn Juu yìí ni wọ́n pa Oluwa Jesu ati àwọn wolii, tí wọ́n sì fi inúnibíni lé wa jáde. Wọn kò ṣe ohun tí ó wu Ọlọrun, wọ́n sì ń lòdì sí àwọn ohun tí ó lè ṣe eniyan ní anfaani.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan