Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Marku 11:1 - Yoruba Bible

1 Nígbà tí wọ́n súnmọ́ Jerusalẹmu, nítòsí Bẹtifage ati Bẹtani, ní orí Òkè Olifi, ó rán meji ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 NIGBATI nwọn si sunmọ eti Jerusalemu, leti Betfage ati Betani, li òke Olifi, o rán meji ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Bí wọ́n ti súnmọ́ Betfage àti Betani ní ẹ̀yìn odi ìlú Jerusalẹmu, wọ́n dé orí òkè olifi. Jesu rán méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ síwájú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Marku 11:1
14 Iomraidhean Croise  

Ṣugbọn Dafidi gun gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè olifi lọ, láì wọ bàtà, ó ń sọkún bí ó ti ń lọ, ó sì fi aṣọ bo orí rẹ̀ láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn. Gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀, tí wọ́n ń bá a lọ náà fi aṣọ bo orí wọn, wọ́n sì ń sọkún bí wọ́n ti ń lọ.


Tó bá di àkókò náà, yóo dúró lórí òkè olifi tí ó wà ní apá ìlà oòrùn Jerusalẹmu; òkè olifi yóo sì pín sí meji. Àfonífojì tí ó gbòòrò yóo sì wà láàrin rẹ̀ láti apá ìlà oòrùn dé apá ìwọ̀ oòrùn. Apá kan òkè náà yóo lọ ìhà àríwá, apá keji yóo sì lọ sí ìhà gúsù.


Ó bá fi wọ́n sílẹ̀, ó sì jáde kúrò lọ sí Bẹtani. Níbẹ̀ ni ó gbé sùn.


Nígbà tí Jesu jókòó lórí Òkè Olifi, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọ́n bi í pé, “Sọ fún wa, nígbà wo ni gbogbo èyí yóo ṣẹlẹ̀, kí sì ni àmì àkókò wíwá rẹ ati ti òpin ayé?”


Lẹ́yìn náà, wọ́n kọ orin kan, wọ́n bá jáde lọ sórí Òkè Olifi.


ó sọ fún wọn pé, “Ẹ lọ sí abúlé tí ẹ̀ ń wò ní ọ̀kánkán yìí, bí ẹ bá ti wọ inú rẹ̀, ẹ óo rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan tí ẹnikẹ́ni kò gùn rí, tí wọ́n so mọ́ èèkàn, ẹ tú u, kí ẹ fà á wá.


Nígbà tí Jesu jókòó ní orí Òkè Olifi, tí ó dojú kọ Tẹmpili, Peteru, Jakọbu, Johanu ati Anderu bi í níkọ̀kọ̀ pé,


Ó bá rán meji ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó wí fún wọn pé, “Ẹ lọ sí inú ìlú, ọkunrin kan tí ó ru ìkòkò omi yóo pàdé yín, ẹ tẹ̀lé e.


Ó pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mejila, ó rán wọn lọ ní meji-meji, ó fi àṣẹ fún wọn lórí àwọn ẹ̀mí èṣù.


Ni olukuluku wọn bá lọ sí ilé wọn; ṣugbọn Jesu lọ sí Òkè Olifi.


Wọ́n pada sí Jerusalẹmu láti orí òkè tí à ń pè ní Òkè Olifi. Òkè náà súnmọ́ Jerusalẹmu, kò tó ibùsọ̀ kan sí ìlú.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan