Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Marku 10:2 - Yoruba Bible

2 Àwọn Farisi bá jáde wá, wọ́n ń bi í bí ó bá tọ́ kí ọkunrin kọ iyawo rẹ̀ sílẹ̀. Wọ́n fi ìbéèrè yìí dán an wò ni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

2 Awọn Farisi si tọ̀ ọ wá, nwọn ndán a wò, nwọn si bi i lẽre, wipe, O tọ́ fun ọkunrin ki o fi aya rẹ̀ silẹ?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Àwọn Farisi kan tọ̀ ọ́ wá, láti dán an wò. Wọ́n béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ǹjẹ́ ó ha tọ̀nà fún ènìyàn láti kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Marku 10:2
25 Iomraidhean Croise  

“Mo kórìíra ìkọ̀sílẹ̀ láàrin tọkọtaya, mo kórìíra irú ìwà ìkà bẹ́ẹ̀ sí olólùfẹ́ ẹni. Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra, kí ẹ má ṣe jẹ́ alaiṣootọ sí aya yín. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun wí!”


Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sọ fún un pé, “Ǹjẹ́ o mọ̀ pé nígbà tí àwọn Farisi gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ, ó bí wọn ninu?”


Àwọn Farisi ati àwọn Sadusi wá sọ́dọ̀ Jesu, wọ́n ń dán an wò, wọ́n ní kí ó fi àmì láti ọ̀run han àwọn.


Àwọn Farisi wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n ń dán an wò; wọ́n bi í pé, “Ǹjẹ́ ó tọ̀nà pé kí ọkunrin kọ iyawo rẹ̀ sílẹ̀ fún ìdí kankan?”


Ọ̀kan ninu wọn tí ó jẹ́ amòfin, bi í ní ìbéèrè kan láti fi dẹ ẹ́, pé,


“Ẹ gbé! Ẹ̀yin amòfin ati ẹ̀yin Farisi, ẹ̀yin alárèékérekè wọnyi. Nítorí ẹ ti ìlẹ̀kùn ìjọba ọ̀run mọ́ àwọn eniyan, ẹ̀yin fúnra yín kò wọlé, bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí wọ́n fẹ́ wọlé, ẹ kò jẹ́ kí wọ́n wọlé. [


Ṣugbọn àwọn Farisi ń sọ pé, “Agbára olórí àwọn ẹ̀mí èṣù ni ó fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.”


Nígbà tí Jesu dìde kúrò níbẹ̀, ó lọ sí agbègbè Judia, ó rékọjá sí òdìkejì odò Jọdani. Ọpọlọpọ àwọn eniyan tún lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀, ó tún ń kọ́ wọn.


Ó dá wọn lóhùn pé, “Kí ni Mose pa láṣẹ fun yín?”


Àwọn Farisi jáde lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n ń dán an wò nípa fífi ọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò, wọ́n ní kí ó fi àmì láti ọ̀run hàn wọ́n.


Jesu bá kìlọ̀ fún wọn pé, “Ẹ kíyèsára kí ẹ sì ṣọ́ra fún ìwúkàrà àwọn Farisi ati ìwúkàrà Hẹrọdu.”


Oluwa wá sọ fún un pé, “Ẹ̀yin Farisi a máa fọ òde kọ́ọ̀bù ati àwo oúnjẹ, ṣugbọn inú yín kún fún ìwà ipá ati nǹkan burúkú!


Nígbà tí àwọn Farisi tí wọ́n fẹ́ràn owó gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí, ńṣe ni wọ́n ń yínmú sí i.


Àwọn Farisi ati àwọn amòfin tí wọ́n wà ninu ẹgbẹ́ wọn wá ń kùn sí Jesu. Wọ́n bi í pé, “Kí ló dé tí o fi ń bá àwọn agbowó-odè ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹ, tí ò ń bá wọn mu?”


Àwọn amòfin ati àwọn Farisi ń ṣọ́ Jesu bí yóo ṣe ìwòsàn ní Ọjọ́ Ìsinmi kí wọ́n lè rí ẹ̀sùn fi kàn án.


Ṣugbọn àwọn Farisi ati àwọn amòfin kọ ìlànà Ọlọrun fún wọn, wọn kò ṣe ìrìbọmi ti Johanu.


Àwọn olórí alufaa ati àwọn Farisi bá pe ìgbìmọ̀, wọ́n ní, “Kí ni a óo ṣe o, nítorí ọkunrin yìí ń ṣe iṣẹ́ ìyanu pupọ?


Àwọn olórí alufaa ati àwọn Farisi ti pàṣẹ pé ẹnikẹ́ni tí ó bá mọ ibi tí Jesu wà, kí ó wá sọ, kí wọ́n lè mú un.


Àwọn Farisi gbọ́ pé àwọn eniyan ń sọ ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ báyìí láàrin ara wọn nípa Jesu. Àwọn olórí alufaa ati àwọn Farisi wá rán àwọn ẹ̀ṣọ́ Tẹmpili pé kí wọ́n lọ mú Jesu wá.


Ṣé kò ṣá sí ẹnikẹ́ni ninu àwọn aláṣẹ ati àwọn Farisi tí ó gbà á gbọ́?


Wọ́n sọ èyí láti fi ká ọ̀rọ̀ mọ́ ọn lẹ́nu ni kí wọ́n lè fi ẹ̀sùn kàn án. Jesu bá bẹ̀rẹ̀, ó ń fi ìka kọ nǹkan sórí ilẹ̀.


Bẹ́ẹ̀ ni kí á má ṣe dán Oluwa wò, bí àwọn mìíràn ninu wọn ti dán an wò, tí ejò fi ṣán wọn pa.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan