Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Marku 10:1 - Yoruba Bible

1 Nígbà tí Jesu dìde kúrò níbẹ̀, ó lọ sí agbègbè Judia, ó rékọjá sí òdìkejì odò Jọdani. Ọpọlọpọ àwọn eniyan tún lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀, ó tún ń kọ́ wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 O si dide kuro nibẹ̀, o si wá si ẹkùn Judea niha oke odò Jordani: awọn enia si tún tọ̀ ọ wá; bi iṣe rẹ̀ ti ri, o si tún nkọ́ wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Nígbà náà, Jesu kúrò níbẹ̀, ó sì wá sí ẹkùn Judea níhà òkè odò Jordani. Àwọn ènìyàn sì tún tọ̀ ọ́ wá, bí i ìṣe rẹ̀, ó sì kọ́ wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Marku 10:1
17 Iomraidhean Croise  

Yàtọ̀ sí pé ọ̀jọ̀gbọ́n náà gbọ́n, ó tún kọ́ àwọn eniyan ní ìmọ̀. Ó wádìí àwọn òwe fínnífínní, ó sì tò wọ́n lẹ́sẹẹsẹ.


Wọ́n ti yíjú kúrò lọ́dọ̀ mi, wọ́n sì kẹ̀yìn sí mi. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti kọ́ wọn ni àkọ́túnkọ́, wọn kò gba ẹ̀kọ́.


Jesu bá sọ fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ jáde wá mú mi pẹlu idà ati kùmọ̀ bí ìgbà tí ẹ wá mú olè. Ojoojumọ ni mò ń jókòó ninu Tẹmpili láti kọ́ àwọn eniyan. Ẹ kò mú mi nígbà náà!


Jesu wá ń kiri gbogbo Galili, ó ń kọ́ àwọn eniyan ninu ilé ìpàdé wọn, ó ń waasu ìyìn rere ìjọba Ọlọrun, ó tún ń wo oríṣìíríṣìí àrùn sàn lára àwọn eniyan.


Wọ́n lọ sí Kapanaumu. Ní Ọjọ́ Ìsinmi àwọn Juu, Jesu lọ sí ilé ìpàdé, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ àwọn eniyan.


Àwọn Farisi bá jáde wá, wọ́n ń bi í bí ó bá tọ́ kí ọkunrin kọ iyawo rẹ̀ sílẹ̀. Wọ́n fi ìbéèrè yìí dán an wò ni.


Bí Jesu ti ń kọ́ àwọn eniyan ninu Tẹmpili, ó bèèrè pé, “Báwo ni àwọn amòfin ṣe wí pé ọmọ Dafidi ni Kristi?


Lojoojumọ ni mo wà pẹlu yín ninu Tẹmpili tí mò ń kọ́ àwọn eniyan, ẹ kò ṣe mú mi nígbà náà. Ṣugbọn kí àkọsílẹ̀ lè ṣẹ ni èyí ṣe rí bẹ́ẹ̀.”


Jesu tún jáde lọ sí ẹ̀bá òkun, gbogbo àwọn eniyan ń lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó bá ń kọ́ wọn.


Ó bá ń fi òwe kọ́ wọn ní ọpọlọpọ nǹkan. Ó wí fún wọn ninu ẹ̀kọ́ rẹ̀ pé:


Nígbà tí ó di Ọjọ́ Ìsinmi, ó bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ àwọn eniyan ninu ilé ìpàdé. Ẹnu ya ọpọlọpọ àwọn tí ó gbọ́ ẹ̀kọ́ rẹ̀. Wọ́n ń wí pé, “Níbo ni eléyìí ti kọ́ ẹ̀kọ́? Irú ọgbọ́n wo ni ọgbọ́n tirẹ̀ yìí, tí iṣẹ́ ìyanu ń ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe?


Nígbà tí Jesu jáde ninu ọkọ̀ ó rí ọpọlọpọ eniyan, àánú ṣe é nítorí wọ́n dàbí aguntan tí kò ní olùṣọ́. Ó bá bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn ní ọpọlọpọ nǹkan.


Ẹnu yà á nítorí aigbagbọ wọn. Jesu ń káàkiri gbogbo àwọn abúlé tí ó wà yíká, ó ń kọ́ àwọn eniyan.


Ó tún pada lọ sí òdìkejì odò Jọdani níbi tí Johanu tí ń ṣe ìrìbọmi ní àkọ́kọ́, ó bá ń gbé ibẹ̀.


Lẹ́yìn náà ni ó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ jẹ́ kí á tún pada lọ sí Judia.”


Jesu dá a lóhùn pé, “Ní gbangba ni èmi tí máa ń bá aráyé sọ̀rọ̀. Ninu ilé ìpàdé ati ninu Tẹmpili ni èmi tí máa ń kọ́ àwọn eniyan nígbà gbogbo, níbi tí gbogbo àwọn Juu ń péjọ sí, n kò sọ ohunkohun níkọ̀kọ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan