Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Marku 1:6 - Yoruba Bible

6 Irun ràkúnmí ni wọ́n fi hun aṣọ tí Johanu wọ̀, ọ̀já ìgbànú aláwọ ni ó gbà mọ́ ìdí, eṣú ni ó ń jẹ, ó sì ń lá oyin ìgàn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

6 Johanu si wọ̀ aṣọ irun ibakasiẹ, o si dì amure awọ mọ ẹgbẹ rẹ̀; o si njẹ ẽṣú ati oyin ìgan.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

6 Johanu sì wọ aṣọ irun ìbákasẹ. Ó sì di àmùrè awọ mọ́ ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Eṣú àti oyin ìgàn sì ni oúnjẹ rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Marku 1:6
6 Iomraidhean Croise  

Wọ́n dáhùn pé, “Ọkunrin náà wọ aṣọ tí wọ́n fi awọ ẹranko ṣe, ó sì di àmùrè awọ mọ́ ẹ̀gbẹ́.” Ọba dáhùn pé, “Elija ará Tiṣibe ni.”


Ẹ lè jẹ àwọn wọnyi ninu wọn: Oríṣìíríṣìí eṣú ati oríṣìíríṣìí ìrẹ̀ ati oríṣìíríṣìí tata.


Nígbà tí àkókò bá tó, ojú yóo ti olukuluku wolii fún ìran tí ó rí nígbà tí ó bá ń sọ àsọtẹ́lẹ̀, kò sì ní wọ aṣọ onírun mọ́ láti fi tan eniyan jẹ.


Johanu yìí wọ aṣọ tí a fi irun ràkúnmí hun, ọ̀já ìgbànú aláwọ ni ó gbà mọ́ ìdí. Oúnjẹ rẹ̀ ni ẹṣú ati oyin ìgàn.


Gbogbo eniyan ilẹ̀ Judia ati ti ìlú Jerusalẹmu jáde tọ̀ ọ́ lọ, wọ́n ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn, ó sì ń ṣe ìrìbọmi fún wọn ninu odò Jọdani.


Ó ń waasu pé, “Ẹnìkan tí ó jù mí lọ ń bọ̀ lẹ́yìn mi, n kò tó bẹ̀rẹ̀ láti tú okùn bàtà rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan