Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Marku 1:2 - Yoruba Bible

2 Gẹ́gẹ́ bí wolii Aisaya ti kọ ọ́ tẹ́lẹ̀ ni ó rí: “Ọlọrun ní, ‘Wò ó! Mo rán oníṣẹ́ mi ṣiwaju rẹ òun ni yóo palẹ̀ mọ́ dè ọ́.’

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

2 Bi a ti kọ ọ ninu iwe woli Isaiah: Kiyesi i, mo rán onṣẹ mi ṣiwaju rẹ, ẹniti yio tún ọ̀na rẹ ṣe niwaju rẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé wòlíì Isaiah pé: “Èmi yóò ran oníṣẹ́ mi síwájú rẹ, Ẹni tí yóò tún ọ̀nà rẹ ṣe.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Marku 1:2
13 Iomraidhean Croise  

Nígbà náà ni mo wí pé, “Wò ó, mo dé; a ti kọ nípa mi sinu ìwé pé:


OLUWA ní, “Wò ó! Mo rán òjíṣẹ́ mi ṣiwaju mi láti tún ọ̀nà ṣe fún mi. OLUWA tí ẹ sì ń retí yóo yọ lójijì sinu tẹmpili rẹ̀; iranṣẹ mi, tí ẹ sì tí ń retí pé kí ó wá kéde majẹmu mi, yóo wá.”


Òun ni àkọsílẹ̀ wà nípa rẹ̀ pé: ‘Wò ó! Mo rán oníṣẹ́ mi ṣiwaju rẹ òun ni yóo palẹ̀ mọ́ dè ọ́.’


Wọ́n sọ fún un pé, “Ní Bẹtilẹhẹmu ti ilẹ̀ Judia ni. Nítorí bẹ́ẹ̀ ni ó wà ní àkọsílẹ̀ wolii nì pé.


Ọmọ-Eniyan ń lọ gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ nípa rẹ̀. Ṣugbọn ẹni tí ó fi Ọmọ-Eniyan lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́ gbé! Ìbá sàn fún un bí a kò bá bí i.”


Nígbà náà Jesu sọ fún wọn pé, “Gbogbo yín ni ẹ óo pada lẹ́yìn mi ní alẹ́ yìí, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Ọwọ́ yóo tẹ olùṣọ́-aguntan, gbogbo agbo aguntan ni a óo fọ́nká!’


gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ láti ẹnu àwọn wolii rẹ̀ mímọ́, láti ọjọ́ pípẹ́;


“Ìwọ, ọmọ mi, wolii Ọ̀gá Ògo ni a óo máa pè ọ́, nítorí ìwọ ni yóo ṣáájú Oluwa láti palẹ̀ mọ́ dè é,


Ó mú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila lọ sápá kan, ó sọ fún wọn pé, “Ṣé ẹ rí Jerusalẹmu tí à ń gòkè lọ yìí, gbogbo ohun tí àwọn wolii kọ nípa Ọmọ-Eniyan ni yóo ṣẹ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan