Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Marku 1:16 - Yoruba Bible

16 Bí Jesu ti ń rìn lọ lẹ́bàá òkun Galili, ó rí Simoni ati Anderu arakunrin rẹ̀ tí wọn ń da àwọ̀n sinu òkun, nítorí apẹja ni wọ́n.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

16 Bi o si ti nrìn leti okun Galili, o ri Simoni ati Anderu arakunrin rẹ̀, nwọn nsọ àwọn sinu okun: nitoriti nwọn ṣe apẹja.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

16 Ní ọjọ́ kan, bí Jesu ti ń rìn létí Òkun Galili, Ó rí Simoni àti Anderu arákùnrin rẹ̀, wọ́n ń fi àwọ̀n wọn pẹja torí pé apẹja ni wọ́n.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Marku 1:16
11 Iomraidhean Croise  

Orúkọ àwọn aposteli mejila náà nìwọ̀nyí: Simoni tí ó tún ń jẹ́ Peteru, ati Anderu arakunrin rẹ̀; lẹ́yìn náà Jakọbu ọmọ Sebede, ati Johanu arakunrin rẹ̀.


Àwọn mejila tí ó yàn náà nìyí: Simoni, tí ó sọ ní Peteru,


ati Anderu, Filipi, Batolomiu, Matiu, ati Tomasi, Jakọbu ọmọ Alfeu, Tadiu, ati Simoni, ọmọ ẹgbẹ́ ìbílẹ̀ Kenaani,


Àwọn ni Simoni tí ó sọ ní Peteru ati Anderu arakunrin rẹ̀, Jakọbu ati Johanu, Filipi ati Batolomiu,


Filipi lọ sọ fún Anderu, Anderu ati Filipi bá jọ lọ sọ fún Jesu.


Nígbà náà ni Anderu, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tí ó jẹ́ arakunrin Simoni Peteru sọ fún un pé,


Nígbà tí wọ́n wọ inú ilé, wọ́n lọ sí iyàrá òkè níbi tí wọn ń gbé. Àwọn tí wọ́n jọ ń gbé ni Peteru, Johanu, Jakọbu, Anderu, Filipi, Tomasi, Batolomiu, Matiu, Jakọbu ọmọ Alfeu, Simoni ti ẹgbẹ́ Seloti ati Judasi ọmọ Jakọbu.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan