Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Marku 1:11 - Yoruba Bible

11 Ó sì gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run tí ó wí pé, “Ìwọ ni àyànfẹ́ ọmọ mi, inú mi dùn sí ọ gidigidi.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

11 Ohùn kan si ti ọrun wá, wipe, Iwọ ni ayanfẹ Ọmọ mi, ẹniti inu mi dùn si gidigidi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

11 Ohùn kan sì ti ọ̀run wá wí pé, “Ìwọ ni àyànfẹ́ Ọmọ mi, ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Marku 1:11
19 Iomraidhean Croise  

N óo kéde ohun tí OLUWA pa láṣẹ ní ti èmi ọba; Ó wí fún mi pé, “Ìwọ ni ọmọ mi, lónìí ni mo bí ọ.


OLUWA ní, “Wo iranṣẹ mi, ẹni tí mo gbéró, àyànfẹ́ mi, ẹni tí inú mi dùn sí. Mo ti jẹ́ kí ẹ̀mí mi bà lé e, yóo máa dá ẹjọ́ ẹ̀tọ́ fún àwọn orílẹ̀-èdè.


“Wo ọmọ mi tí mo yàn, àyànfẹ́ mi, ẹni tí ọkàn mi yọ̀ mọ́ Èmi óo fi Ẹ̀mí mi sí i lára, yóo kéde ìdájọ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí kì í ṣe Juu.


Bí ó ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, ìkùukùu kan tí ń tàn bò wọ́n mọ́lẹ̀. Ohùn kan wá láti inú ìkùukùu náà wí pé, “Àyànfẹ́ ọmọ mi nìyí, inú mi dùn sí i. Ẹ máa gbọ́ tirẹ̀.”


Ohùn kan láti ọ̀run wá sọ pé, “Àyànfẹ́ ọmọ mi nìyí, inú mi dùn sí i gidigidi.”


Bí Jesu ti ń jáde kúrò ninu omi, lẹ́sẹ̀ kan náà ó rí Ẹ̀mí Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí àdàbà tí ó bà lé e.


Ìkùukùu kan bá ṣíji bò wọ́n, ohùn kan bá wá láti inú ìkùukùu náà tí ó wí pé, “Èyí ni àyànfẹ́ ọmọ mi, ẹ máa gbọ́ tirẹ̀.”


Ẹ̀mí Mímọ́ fò wálẹ̀ bí àdàbà ó bà lé e lórí. Ohùn kan wá fọ̀ láti ọ̀run pé, “Ìwọ ni àyànfẹ́ Ọmọ mi; inú mi dùn sí ọ gidigidi.”


Ohùn kan ti inú ìkùukùu náà wá, ó ní “Èyí ni àyànfẹ́ ọmọ mi, ẹ máa gbọ́ tirẹ̀!”


Mo ti rí i, mo wá ń jẹ́rìí pé òun ni Ọmọ Ọlọrun.”


Nítorí Ọlọrun fẹ́ aráyé tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kanṣoṣo fúnni, pé kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́ má baà ṣègbé, ṣugbọn kí ó lè ní ìyè ainipẹkun.


Baba tí ó rán mi níṣẹ́ ti jẹ́rìí mi. Ẹnikẹ́ni kò ì tíì gbọ́ ohùn rẹ̀ rí, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò rí i bí ó ti rí rí.


Ní tiwa, a ti gbàgbọ́, a sì ti mọ̀ pé ìwọ ni Ẹni Mímọ́ Ọlọrun.”


Ọmọ rẹ̀ yìí ni Ọlọrun fi agbára Ẹ̀mí Mímọ́ yàn nígbà tí ó jí i dìde kúrò ninu òkú. Òun náà ni Jesu Kristi Oluwa wa,


Baba wa náà ni ó gbà wá lọ́wọ́ agbára òkùnkùn, ó sì mú wa wá sinu ìjọba àyànfẹ́ Ọmọ rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan