Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 8:9 - Yoruba Bible

9 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bi í ní ìtumọ̀ òwe yìí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

9 Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si bi i lẽre, wipe, Kili a le mọ̀ owe yi si?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì bi í léèrè, pé, “Kí ni a lè mọ òwe yìí sí?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 8:9
9 Iomraidhean Croise  

Ẹ jẹ́ kí á mọ̀ ọ́n, ẹ jẹ́ kí á tẹ̀síwájú kí á mọ OLUWA. Dídé rẹ̀ dájú bí àfẹ̀mọ́jú; yóo sì pada wá sọ́dọ̀ wa bí ọ̀wààrà òjò, ati bí àkọ́rọ̀ òjò tí ń bomirin ilẹ̀.”


Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n bi í pé, “Kí ló dé tí o fi ń fi òwe bá àwọn eniyan sọ̀rọ̀?”


“Ẹ gbọ́ ìtumọ̀ òwe afunrugbin.


Nígbà tí Jesu kúrò lọ́dọ̀ àwọn eniyan, ó lọ sinu ilé. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sọ pé, “Ṣe àlàyé òwe èpò inú oko fún wa.”


Peteru sọ fún un pé, “Túmọ̀ òwe yìí fún wa.”


Nígbà tí ó ku òun nìkan, àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀ ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila bèèrè ìtumọ̀ àwọn òwe tí ó fi ń sọ̀rọ̀.


Kì í bá wọn sọ̀rọ̀ láì lo òwe. Ṣugbọn nígbà tí ó bá ku òun ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, a máa túmọ̀ gbogbo rẹ̀ fún wọn.


N kò pè yín ní ọmọ-ọ̀dọ̀ mọ́, nítorí ọmọ-ọ̀dọ̀ kì í mọ ohun tí ọ̀gá rẹ̀ ń ṣe. Ṣugbọn mo pè yín ní ọ̀rẹ́, nítorí ohun gbogbo tí mo ti gbọ́ lọ́dọ̀ Baba mi ni mo ti fihàn yín.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan