Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 8:8 - Yoruba Bible

8 Irúgbìn mìíràn bọ́ sórí ilẹ̀ dáradára, ó dàgbà, ó sì so èso. Irúgbìn kọ̀ọ̀kan so ọgọọgọrun-un.” Nígbà tí ó sọ báyìí tán, ó wá tún sọ pé, “Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ràn, kí ó gbọ́!”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

8 Omiran si bọ́ si ilẹ rere, o si rú soke, o si so eso ọrọrun. Nigbati o si wi nkan wọnyi tan, o nahùn wipe, Ẹniti o ba li etí lati fi gbọ́, ki o gbọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 Òmíràn sì bọ́ sí ilẹ̀ rere, ó sì hù sókè, ó sì so èso ọ̀rọ̀ọ̀rún ju èyí ti a gbin lọ.” Nígbà tí ó sì wí nǹkan wọ̀nyí tán, ó pariwo sókè pé, “Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́, kí ó gbọ́!”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 8:8
25 Iomraidhean Croise  

Isaaki dá oko ní ilẹ̀ náà, láàrin ọdún kan ṣoṣo ó rí ìkórè ìlọ́po lọ́nà ọgọrun-un (100) ohun tí ó gbìn nítorí OLUWA bukun un.


Ati etí tí ń gbọ́ràn, ati ojú tí ń ríran, OLUWA ló dá ekinni-keji wọn.


Ọgbọ́n ń pe eniyan, òye ń pariwo.


Ẹ tẹ́tí sílẹ̀ kí ẹ gbọ́, ẹ má gbéraga nítorí pé OLUWA ló sọ̀rọ̀.


Ẹ kò fetí sílẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nígbà gbogbo ni OLUWA ń rán àwọn wolii, iranṣẹ rẹ̀, si yín, tí wọn ń sọ fun yín pé


Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ràn, kí ó gbọ́.


Ṣugbọn èyí tí a fún sórí ilẹ̀ rere ni ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí ọ̀rọ̀ náà yé, tí ó wá ń so èso, nígbà mìíràn, ọgọrun-un; nígbà mìíràn, ọgọta; nígbà mìíràn, ọgbọ̀n.”


Àwọn mìíràn dàbí irúgbìn tí a fún sórí ilẹ̀ rere. Àwọn yìí ni ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí wọ́n gbà á, tí wọ́n sì so èso, òmíràn ọgbọọgbọn, òmíràn ọgọọgọta, òmíran ọgọọgọrun-un.”


Bí ẹnikẹ́ni bá ní etí láti fi gbọ́ràn, kí ó gbọ́.”


Irúgbìn mìíràn bọ́ sí ilẹ̀ tí ó dára, wọ́n yọ sókè, wọ́n ń dàgbà, wọ́n sì ń so èso, òmíràn ọgbọ̀n, òmíràn ọgọta, òmíràn ọgọrun-un.”


Ẹni tí ó bá ní etí láti gbọ́ràn, kí ó gbọ́.”]


Kó wúlò fún oko tabi fún ààtàn mọ́ àfi kí á dà á sóde. Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ràn, kí ó gbọ́!”


Àwọn ti ilẹ̀ dáradára ni àwọn tí ó fi ọkàn rere ati ọkàn mímọ́ gba ọ̀rọ̀ náà, wọ́n sì dì í mú ṣinṣin, wọ́n sì so èso nípa ìfaradà.


Irúgbìn mìíràn bọ́ sáàrin ẹ̀gún. Nígbà tí òun ati ẹ̀gún jọ dàgbà, ń ṣe ni ẹ̀gún fún un pa.


Nítorí òun ni ó dá wa bí a ti rí, ó dá wa fún iṣẹ́ rere nípasẹ̀ Kristi Jesu, àwọn iṣẹ́ tí Ọlọrun ti ṣe tẹ́lẹ̀, pé kí á máa ṣe.


A tún ń gbadura pé kí ìgbé-ayé yín lè jẹ́ èyí tí ó wu Oluwa lọ́nà gbogbo, kí iṣẹ́ rere yín máa pọ̀ sí i, kí ẹ máa tẹ̀síwájú ninu ìmọ̀ Ọlọrun.


Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́!


“Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ. “Ẹni tí ó bá ṣẹgun kò ní kú ikú keji.


“Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ. “Ẹni tí ó bá ṣẹgun ni n óo fún ní àṣẹ láti jẹ ninu èso igi ìyè tí ó wà ninu ọgbà Ọlọrun.


“Ẹni tí ó bá ní etí kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń bá àwọn ìjọ sọ.


“Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan