Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 8:7 - Yoruba Bible

7 Irúgbìn mìíràn bọ́ sáàrin ẹ̀gún. Nígbà tí òun ati ẹ̀gún jọ dàgbà, ń ṣe ni ẹ̀gún fún un pa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

7 Omiran si bọ́ sinu ẹgún; ẹgún si ba a rú soke, o si fun u pa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Òmíràn sì bọ́ sínú ẹ̀gún; ẹ̀gún sì dàgbà pẹ̀lú rẹ̀ sókè, ó sì fún un pa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 8:7
11 Iomraidhean Croise  

Ẹ̀gún ati òṣùṣú ni ilẹ̀ yóo máa hù jáde fún ọ, ewéko ni o óo sì máa jẹ.


Nítorí pé OLUWA sọ fún àwọn ará Juda ati àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu pé, “Ẹ tún oko yín tí ẹ ti patì tẹ́lẹ̀ kọ, ẹ má sì gbin èso sáàrin ẹ̀gún.


Ti ààrin igi ẹlẹ́gùn-ún ni ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí àníyàn ayé yìí ati ìtànjẹ ọrọ̀ fún ọ̀rọ̀ náà pa, tí kò fi so èso.


Àwọn irúgbìn mìíràn bọ́ sáàrin igi ẹlẹ́gùn-ún. Nígbà tí wọ́n yọ, ẹ̀gún fún wọn pa.


Irúgbìn mìíràn bọ́ sí orí ilẹ̀ ẹlẹ́gùn-ún. Nígbà tí ẹ̀gún dàgbà, ó fún wọn pa, nítorí náà wọn kò so èso.


“Ẹ ṣọ́ra yín, kí ẹ má jẹ́ kí ayẹyẹ, tabi ìfiṣòfò, tabi ọtí mímu, ati àníyàn ayé gba ọkàn yín, tí ó fi jẹ́ pé lójijì ni ọjọ́ náà yóo dé ba yín bí ìgbà tí tàkúté bá mú ẹran.


Àwọn tí ó bọ́ sáàrin ẹ̀gún ni àwọn tí ó gbọ́, ṣugbọn àkólékàn ayé, ìlépa ọrọ̀, ati ìgbádùn ayé fún ọ̀rọ̀ náà pa, wọn kò lè dàgbà láti so èso.


Irúgbìn mìíràn bọ́ sórí àpáta. Nígbà tí ó hù, ó bá gbẹ nítorí kò sí omi.


Irúgbìn mìíràn bọ́ sórí ilẹ̀ dáradára, ó dàgbà, ó sì so èso. Irúgbìn kọ̀ọ̀kan so ọgọọgọrun-un.” Nígbà tí ó sọ báyìí tán, ó wá tún sọ pé, “Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ràn, kí ó gbọ́!”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan