Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 7:2 - Yoruba Bible

2 Ọ̀gágun kan ní ẹrú kan tí ó ṣàìsàn, ó fẹ́rẹ̀ kú. Ẹrú náà ṣe ọ̀wọ́n fún un.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

2 Ọmọ-ọdọ balogun ọrún kan, ti o ṣọwọn fun u, o ṣaisàn, o nkú lọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Ọmọ ọ̀dọ̀ balógun ọ̀rún kan, tí ó ṣọ̀wọ́n fún un, ṣàìsàn, ó sì ń kú lọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 7:2
24 Iomraidhean Croise  

ó sọ pé, “Ọpẹ́ ni fún ọ OLUWA Ọlọrun Abrahamu, oluwa mi, tí kò gbàgbé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ ati òdodo rẹ̀ sí oluwa mi. Ní tèmi, OLUWA ti tọ́ mi sọ́nà tààrà, sí ilé àwọn ìbátan oluwa mi.”


Níbẹ̀ ni Debora, olùtọ́jú Rebeka kú sí, wọ́n sì sin ín sí abẹ́ igi oaku kan ní ìhà gúsù Bẹtẹli, Jakọbu bá sọ ibẹ̀ ní Aloni-bakuti.


Bí mo bá rìn ní ọ̀nà aiṣododo, tí mo sì yára láti sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn,


Bí eniyan bá kẹ́ ẹrú ní àkẹ́jù, yóo ya ìyàkuyà níkẹyìn.


Nígbà tí ọ̀gágun ati àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀ tí wọn ń ṣọ́ Jesu rí ilẹ̀ tí ó mì ati gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ẹ̀rù bà wọ́n pupọ. Wọ́n ní, “Nítòótọ́ Ọmọ Ọlọrun ni ọkunrin yìí.”


Nígbà tí ọ̀gágun náà rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ó yin Ọlọrun lógo, ó ní, “Lóòótọ́, olódodo ni ọkunrin yìí.”


Nígbà tí Jesu parí ọ̀rọ̀ tí ó ń bá àwọn eniyan sọ, ó wọ inú ìlú Kapanaumu lọ.


Nígbà tí ó gbọ́ nípa Jesu, ó rán àwọn àgbààgbà Juu kan sí i pé kí wọn bá òun bẹ̀ ẹ́ kí ó wá wo ẹrú òun sàn.


nítorí ọmọdebinrin rẹ̀ kan ṣoṣo tí ó ní ń kú lọ. Ọmọ yìí tó ọmọ ọdún mejila. Bí Jesu ti ń lọ àwọn eniyan ń bì lù ú níhìn-ín lọ́hùn-ún.


Ọkunrin kan wà ní Kesaria tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kọniliu. Ó jẹ́ balogun ọ̀rún ti ẹgbẹ́ tí à ń pè ní Ẹgbẹ́ Ọmọ Ogun Itali.


Bí angẹli tí ó ń bá a sọ̀rọ̀ ti lọ tán, ó pe meji ninu àwọn iranṣẹ rẹ̀ ati ọmọ-ogun olùfọkànsìn kan, ọ̀kan ninu àwọn tí ó máa ń dúró tì í tímọ́tímọ́.


Nígbà tí balogun ọ̀rún gbọ́, ó lọ sọ́dọ̀ ọ̀gágun, ó bi í pé, “Kí lẹ fẹ́ ṣe? Ọmọ ìbílẹ̀ Romu ni ọkunrin yìí o!”


Paulu wá pe ọ̀kan ninu àwọn balogun ọ̀rún, ó ní, “Mú ọdọmọkunrin yìí lọ sọ́dọ̀ ọ̀gágun, nítorí ó ní ọ̀rọ̀ kan láti sọ fún un.”


Nígbà tí wọ́n pinnu láti fi wá ranṣẹ sí Itali, wọ́n fi Paulu ati àwọn ẹlẹ́wọ̀n mìíràn lé balogun ọ̀rún kan tí ó ń jẹ́ Juliọsi lọ́wọ́, ó jẹ́ ọ̀gágun ti ẹgbẹ́ kan tí wọn ń pè ní Ọmọ-ogun Augustu.


Ní ọjọ́ keji a gúnlẹ̀ ní Sidoni. Juliọsi ṣe dáradára sí Paulu. Ó jẹ́ kí ó lọ sọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, kí wọ́n fún un ní àwọn nǹkan tí ó nílò.


Ṣugbọn balogun ọ̀rún kò jẹ́ kí àwọn ọmọ-ogun ṣe ìfẹ́ inú wọn, nítorí pé ó fẹ́ mú Paulu gúnlẹ̀ ní alaafia. Ó pàṣẹ pé kí àwọn tí ó bá lè lúwẹ̀ẹ́ kọ́kọ́ bọ́ sómi, kí wọ́n lúwẹ̀ẹ́ lọ sí èbúté.


Ẹ̀yin ẹrú, ẹ máa gbọ́ràn sí àwọn olówó yín lẹ́nu ninu ohun gbogbo. Kí ó má jẹ́ pé nígbà tí wọn bá ń ṣọ́ yín nìkan ni ẹ óo máa ṣiṣẹ́, bí ìgbà tí ó jẹ́ pé eniyan ni ẹ̀ ń fẹ́ tẹ́ lọ́rùn. Ṣugbọn ẹ fi gbogbo ara ṣiṣẹ́, ní ìbẹ̀rù Oluwa.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan