Luku 7:12 - Yoruba Bible12 Nígbà tí wọ́n súnmọ́ ẹnu odi ìlú náà, wọ́n rí òkú ọmọ kan tí wọn ń gbé jáde. Ọmọ yìí nìkan náà ni ìyá rẹ̀ bí. Opó sì ni ìyá náà. Ọ̀pọ̀ àwọn eniyan láti inú ìlú wá pẹlu obinrin náà. Faic an caibideilBibeli Mimọ12 Bi o si ti sunmọ ẹnu bode ilu na, si kiyesi i, nwọn ngbé okú kan jade, ọmọ kanṣoṣo na ti iya rẹ̀, o si jẹ opó: ọ̀pọ ijọ enia ilu na si wà pẹlu rẹ̀. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní12 Bí ó sì ti súnmọ́ ẹnu ibodè ìlú náà, sì kíyèsi i, wọ́n ń gbé òkú ọkùnrin kan jáde, ọmọ kan ṣoṣo náà tí ìyá rẹ̀ bí, ó sì jẹ́ opó: ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn ìlú náà sì wà pẹ̀lú rẹ̀. Faic an caibideil |
Nisinsinyii, kabiyesi, gbogbo àwọn eniyan mi ni wọ́n ti kẹ̀yìn sí mi. Wọ́n ní dandan kí ń fa ọmọ mi kan yòókù kalẹ̀ fún àwọn, kí wọ́n lè pa á nítorí arakunrin rẹ̀ tí ó pa. Bí mo bá gbà fún wọn, kò ní sí ẹni tí yóo jogún ọkọ mi, wọn yóo já ìrètí mi kan tí ó kù kulẹ̀, kò sì ní sí ọmọkunrin tí yóo gbé orúkọ ọkọ mi ró, tí orúkọ náà kò fi ní parun.”
Obinrin náà dáhùn pé, “OLUWA Ọlọrun rẹ ń gbọ́, n kò ní oúnjẹ rárá. Gbogbo ohun tí mo ní kò ju ẹ̀kúnwọ́ ìyẹ̀fun kan lọ, tí ó wà ninu àwokòtò kan; ati ìwọ̀nba òróró olifi díẹ̀, ninu kólòbó kan. Igi ìdáná díẹ̀ ni mò ń wá níhìn-ín, kí n fi se ìwọ̀nba oúnjẹ díẹ̀ tí ó kù, fún èmi ati ọmọ mi; pé kí a jẹ ẹ́, kí a sì máa dúró de ọjọ́ ikú.”