Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 6:1 - Yoruba Bible

1 Ní Ọjọ́ Ìsinmi kan, bí Jesu ti ń la oko ọkà kan kọjá, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí já ọkà, wọ́n ń fi ọwọ́ ra á, wọ́n bá ń jẹ ẹ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 O si ṣe li ọjọ isimi keji lẹhin ekini, Jesu kọja larin oko ọkà; awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si nya ipẹ́ ọkà, nwọn nfi ọwọ́ ra a jẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Ní ọjọ́ ìsinmi kejì, Jesu ń kọjá láàrín oko ọkà; àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì ń ya ìpẹ́ ọkà, wọ́n sì ń jẹ ẹ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 6:1
10 Iomraidhean Croise  

“Ọjọ́ meje ni ẹ óo fi jẹ burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu. Láti ọjọ́ kinni ni kí ẹ ti mú gbogbo ìwúkàrà kúrò ninu ilé yín, nítorí pé bí ẹnikẹ́ni bá jẹ burẹdi tí ó ní ìwúkàrà ninu láti ọjọ́ kinni títí di ọjọ́ keje, a kò ní ka irú ẹni bẹ́ẹ̀ kún àwọn eniyan Israẹli mọ́.


“Ẹ óo ka ọ̀sẹ̀ meje, bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ keji ọjọ́ ìsinmi tí ẹ mú ìtí ọkà fún ẹbọ fífì wá fún OLUWA.


Ní ọjọ́ kinni, ẹ níláti ní àpèjọ, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ tí ó bá lágbára.


Kò sí ẹni tí ó bá ti mu ọtí tí ó mú, tíí fẹ́ mu ọtí àṣẹ̀ṣẹ̀pọn. Nítorí yóo sọ pé, ‘Ọtí tí ó mú ni ó dára.’ ”


Nígbà tí ó di Ọjọ́ Ìsinmi mìíràn, Jesu wọ inú ilé ìpàdé lọ, ó ń kọ́ àwọn eniyan. Ọkunrin kan wà níbẹ̀ tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ rọ.


“Ẹ óo ka ọ̀sẹ̀ meje, bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ tí ẹ kọ́kọ́ ti dòjé bọ inú oko ọkà, tí ẹ sì bẹ̀rẹ̀ sí gé e.


Nígbà tí ẹ bá ń kọjá lọ ní oko ọkà ẹlòmíràn, tí wọn kò tíì kórè, ẹ lè fi ọwọ́ ya ìwọ̀nba tí ẹ lè jẹ, ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ fi dòjé gé ọkà ọlọ́kà.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan