Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 5:3 - Yoruba Bible

3 Jesu bá wọ inú ọ̀kan ninu àwọn ọkọ̀ náà tí ó jẹ́ ti Simoni, ó ní kí wọ́n tù ú kúrò létí òkun díẹ̀. Ni ó bá jókòó ninu ọkọ̀, ó ń kọ́ àwọn eniyan.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 O si wọ̀ ọkan ninu awọn ọkọ̀ na, ti iṣe ti Simoni, o si bẹ̀ ẹ ki o tẹ̀ si ẹhin diẹ kuro ni ilẹ. O si joko, o si nkọ́ ijọ enia lati inu ọkọ̀ na.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Ó sì wọ ọ̀kan nínú àwọn ọkọ̀ náà, tí í ṣe ti Simoni, ó sì bẹ̀ ẹ́ kí ó tì í sí ẹ̀yìn díẹ̀ kúrò ní ilẹ̀. Ó sì jókòó, ó sì ń kọ́ ìjọ ènìyàn láti inú ọkọ̀ náà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 5:3
8 Iomraidhean Croise  

Bí Jesu ti ń rìn lọ lẹ́bàá òkun Galili, ó rí àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò meji kan, Simoni tí ó tún ń jẹ́ Peteru ati Anderu arakunrin rẹ̀. Wọ́n ń da àwọ̀n sí inú òkun, nítorí apẹja ni wọ́n.


Nítorí ó wo ọpọlọpọ sàn tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn aláìsàn ń ti ara wọn, kí wọ́n lè fi ọwọ́ kàn án.


Ó bá sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọn tọ́jú ọkọ̀ ojú omi kan sí ìtòsí nítorí àwọn eniyan, kí wọn má baà fún un pa.


Ó rí àwọn ọkọ̀ meji létí òkun. Àwọn apẹja ti kúrò ninu àwọn ọkọ̀ yìí, wọ́n ń fọ àwọ̀n wọn.


Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, ó tún lọ sí Tẹmpili. Gbogbo àwọn eniyan ń lọ sọ́dọ̀ rẹ̀. Ó bá jókòó, ó ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan