Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 5:1 - Yoruba Bible

1 Ní àkókò kan, bí Jesu ti dúró létí òkun Genesarẹti, ọ̀pọ̀ eniyan péjọ sọ́dọ̀ rẹ̀ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọrun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 O si ṣe, nigbati ijọ enia ṣù mọ́ ọ lati gbọ́ ọ̀rọ Ọlọrun, ti o si duro leti adagun Genesareti,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Ó sì ṣe, nígbà tí ìjọ ènìyàn súnmọ́ ọn láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí ó sì dúró létí adágún Genesareti.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 5:1
21 Iomraidhean Croise  

Yóo lọ sí ìhà gúsù sí Ribila ní ìhà ìlà oòrùn Aini títí lọ sí àwọn òkè tí wọ́n wà létí ìhà ìlà oòrùn Òkun-Kinereti.


Láti àkókò tí Johanu Onítẹ̀bọmi ti bẹ̀rẹ̀ sí waasu títí di ìsinsìnyìí ni àwọn alágbára ti gbógun ti ìjọba ọ̀run, wọ́n sì fẹ́ fi ipá gbà á.


Lẹ́yìn tí wọ́n ti gúnlẹ̀, wọ́n dé ilẹ̀ Genesarẹti.


Ó bá sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọn tọ́jú ọkọ̀ ojú omi kan sí ìtòsí nítorí àwọn eniyan, kí wọn má baà fún un pa.


Jesu tún bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ àwọn eniyan lẹ́bàá òkun. Ogunlọ́gọ̀ eniyan péjọ pọ̀ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi níláti bọ́ sin ọkọ̀ ojú omi kan, ó bá jókòó níbẹ̀ lójú omi. Gbogbo àwọn eniyan wà ní èbúté, wọ́n jókòó lórí iyanrìn.


Jesu bá bá a lọ. Bí ó ti ń lọ, ọpọlọpọ eniyan ń tẹ̀lé e, wọ́n ń fún un lọ́tùn-ún lósì.


Nígbà tí wọ́n la òkun já, wọ́n dé Genesarẹti, wọ́n bá gúnlẹ̀.


Ní àkókò yìí, ogunlọ́gọ̀ eniyan péjọ; wọ́n pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí wọn fi ń tẹ ara wọn mọ́lẹ̀. Jesu kọ́ bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ̀rọ̀ ná. Ó ní, “Ẹ ṣọ́ ara yín nípa ìwúkàrà àwọn Farisi, àwọn alágàbàgebè.


Ó rí àwọn ọkọ̀ meji létí òkun. Àwọn apẹja ti kúrò ninu àwọn ọkọ̀ yìí, wọ́n ń fọ àwọ̀n wọn.


Ní ọjọ́ kan Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wọ inú ọkọ̀ ojú omi kan, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí á kọjá lọ sí òdìkejì òkun.” Ni wọ́n bá lọ.


Bí wọ́n ti ń wakọ̀ lọ, Jesu bá sùn lọ. Ìjì líle kan bá bẹ̀rẹ̀ lójú òkun, omi bẹ̀rẹ̀ sí ya wọ inú ọkọ̀; ẹ̀mí wọn sì wà ninu ewu.


Àwọn ẹ̀mí èṣù yìí bá jáde kúrò ninu ọkunrin tí à ń wí yìí, wọ́n wọ inú àwọn ẹlẹ́dẹ̀, ni agbo ẹlẹ́dẹ̀ bá sáré láti gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè lọ sí inú òkun, wọ́n bá rì sómi.


Jesu ní, “Ta ni fọwọ́ kàn mí?” Nígbà tí gbogbo wọn sẹ́, Peteru ní, “Ọ̀gá, mélòó-mélòó ni àwọn eniyan tí wọn ń fún ọ, tí wọn ń tì ọ́?”


Ọ̀kan ninu àwọn meji tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Johanu, tí ó tẹ̀lé Jesu ni Anderu arakunrin Simoni Peteru.


Lẹ́yìn èyí, Jesu lọ sí òdìkejì òkun Galili tí ó tún ń jẹ́ òkun Tiberiasi.


ati ilẹ̀ Araba títí kan odò Jọdani. Láti Kinereti títí dé Òkun Araba tí wọn ń pè ní Òkun Iyọ̀, ní ẹsẹ̀ òkè Pisiga ní apá ìlà oòrùn.


Ẹ ranti àwọn aṣiwaju yín, àwọn tí wọ́n mú ọ̀rọ̀ Ọlọrun wá fun yín. Ẹ ronú nípa iṣẹ́ wọn ati bí wọ́n ṣe kú. Kí ẹ ṣe àfarawé igbagbọ wọn.


ati Araba, títí dé òkun Ṣinerotu ní apá ìlà oòrùn, ní ọ̀nà ìlú Beti Jeṣimotu, títí dé òkun Araba, (tí wọ́n tún ń pè ní Òkun Iyọ̀), títí lọ sí apá ìhà gúsù, títí dé ẹsẹ̀ òkè Pisiga.


àfonífojì Beti Nimra, Sukotu, ati Safoni, ìyókù ilẹ̀ ìjọba Sihoni, ọba Heṣiboni. Odò Jọdani ni ààlà ilẹ̀ wọn, ní apá ìsàlẹ̀ òkun Kinereti, lọ sí apá ìlà oòrùn, níkọjá odò Jọdani.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan