Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 4:8 - Yoruba Bible

8 Jesu dá a lóhùn pé, “Ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Oluwa Ọlọrun rẹ ni kí o máa júbà, òun nìkan ni kí o sì máa sìn!’ ”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

8 Jesu si dahùn o si wi fun u pe, Kuro lẹhin mi, Satani, nitoriti a kọwe rẹ̀ pe, Iwọ foribalẹ fun Oluwa Ọlọrun rẹ, on nikanṣoṣo ni ki iwọ ki o si ma sìn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 Jesu sì dáhùn ó sì wí fún un pé, “Kúrò lẹ́yìn mi, Satani, nítorí tí a kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Ìwọ foríbalẹ̀ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, òun nìkan ṣoṣo ni kí ìwọ kí ó sì máa sìn.’ ”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 4:8
14 Iomraidhean Croise  

Ó gbadura pé, “OLUWA Ọlọrun Israẹli, tí ń gbé láàrin àwọn Kerubu, ìwọ nìkan ni Ọlọrun tí ń jọba lórí gbogbo ilẹ̀ ayé, ìwọ ni o dá ayé ati ọ̀run.


Jẹ́ kí wọn mọ̀ pé ìwọ nìkan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ OLUWA, ni Ọ̀gá Ògo lórí gbogbo ayé.


A óo rẹ ọlọ́kàn gíga eniyan sílẹ̀, a óo sì rẹ àwọn onigbeeraga sílẹ̀; OLUWA nìkan ni a óo gbéga ní ọjọ́ náà.


Ṣugbọn Jesu yipada, ó sọ fún Peteru pé, “Kó ara rẹ̀ kúrò níwájú mi, Satani. Ohun ìkọsẹ̀ ni o jẹ́ fún mi, nítorí o kò ro nǹkan ti Ọlọrun, ti eniyan ni ò ń rò.”


Jesu bá dá a lóhùn, ó ní, “Pada kúrò lẹ́yìn mi, Satani. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Oluwa Ọlọrun rẹ ni kí o máa júbà, òun nìkan ni kí o máa sìn.’ ”


Jesu dá a lóhùn pé, “Ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Kì í ṣe oúnjẹ nìkan ni yóo mú kí eniyan wà láàyè.’ ”


Tí o bá júbà mi, tìrẹ ni gbogbo rẹ̀ yóo dà.”


Ẹ bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun yín; ẹ sìn ín, kí ẹ sì súnmọ́ ọn. Orúkọ rẹ̀ ni kí ẹ máa fi búra.


Ẹ gbọdọ̀ bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun yín, kí ẹ sì máa sìn ín. Orúkọ rẹ̀ ni kí ẹ máa fi búra.


Nítorí náà, ẹ fi ara yín sábẹ́ àṣẹ Ọlọrun. Ẹ dojú ìjà kọ Èṣù, yóo sì sálọ kúrò lọ́dọ̀ yín.


Ẹ takò ó pẹlu igbagbọ tí ó dúró gbọningbọnin. Kí ẹ mọ̀ pé àwọn onigbagbọ ẹgbẹ́ yín ń jẹ irú ìyà kan náà níwọ̀n ìgbà tí wọ́n wà ninu ayé.


Ni mo bá dojúbolẹ̀ níwájú rẹ̀, mo júbà rẹ̀. Ó bá sọ fún mi pé, “Èèwọ̀! Má ṣe bẹ́ẹ̀! Iranṣẹ bí ìwọ ati àwọn arakunrin rẹ, tí wọ́n jẹ́rìí igbagbọ ninu Jesu, ni èmi náà. Ọlọrun ni kí o júbà.” Nítorí ẹ̀mí tí ó mú kí eniyan jẹ́rìí igbagbọ ninu Jesu ni ẹ̀mí tí ó wà ninu wolii.


Ṣugbọn ó sọ fún mi pé, “Èèwọ̀! Má ṣe bẹ́ẹ̀! Iranṣẹ ẹlẹgbẹ́ rẹ ni èmi náà ati ti àwọn wolii, arakunrin rẹ, ati ti àwọn tí wọ́n ti pa àwọn ọ̀rọ̀ ìwé yìí mọ́. Ọlọrun ni kí o júbà.”


Samuẹli bá sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Bí ẹ bá fẹ́ pada sọ́dọ̀ OLUWA tọkàntọkàn, ẹ gbọdọ̀ kó gbogbo oriṣa ati gbogbo ère oriṣa Aṣitarotu, tí ó wà lọ́dọ̀ yín dànù; ẹ palẹ̀ ọkàn yín mọ́ fún OLUWA, kí ẹ sì máa sin òun nìkan ṣoṣo; yóo sì gbà yín lọ́wọ́ àwọn ará Filistia.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan