Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 4:6 - Yoruba Bible

6 Ó sọ fún Jesu pé, “Ìwọ ni n óo fún ní gbogbo àṣẹ yìí ati ògo rẹ̀, nítorí èmi ni a ti fi wọ́n lé lọ́wọ́, ẹni tí ó bá sì wù mí ni mo lè fún.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

6 Èṣu si wi fun u pe, Iwọ li emi o fi gbogbo agbara yi ati ogo wọn fun: gbogbo rẹ̀ li a sá ti fifun mi; ẹnikẹni ti o ba si wù mi, emi a fi i fun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

6 Èṣù sì wí fún un pé, “Ìwọ ni èmi ó fi gbogbo agbára yìí àti ògo wọn fún: nítorí á sá ti fi fún mi. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì wù mí, èmi a fi í fún.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 4:6
15 Iomraidhean Croise  

ó bẹ̀rẹ̀ sí fọ́nnu fún wọn bí ọrọ̀ rẹ̀ ti pọ̀ tó, iye àwọn ọmọ rẹ̀, bí ọba ṣe gbé e ga ju gbogbo àwọn ìjòyè ati àwọn olórí yòókù lọ.


OLUWA àwọn ọmọ ogun ni ó pinnu láti ba gbogbo iyì ògo jẹ, ati láti tẹ́ gbogbo àwọn ọlọ́lá ayé.


Isà òkú ti ṣetán, yóo gbé wọn mì, ó ti yanu kalẹ̀. Àwọn ọlọ́lá Jerusalẹmu yóo já sinu rẹ́, ati ọ̀pọ̀ ninu àwọn ará ìlú, ati àwọn tí ń fi ìlú Jerusalẹmu yangàn.


Tí o bá júbà mi, tìrẹ ni gbogbo rẹ̀ yóo dà.”


Àkókò tó fún ìdájọ́ ayé yìí. Nisinsinyii ni a óo lé aláṣẹ ayé yìí jáde.


N kò tún ní ohun pupọ ba yín sọ mọ́, nítorí aláṣẹ ayé yìí ń bọ̀. Kò ní agbára kan lórí mi.


Láti ọ̀dọ̀ èṣù baba yín, ni ẹ ti wá. Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ baba yín ni ẹ ń fẹ́ ṣe. Òun ní tirẹ̀, apànìyàn ni láti ìbẹ̀rẹ̀, ara rẹ̀ kọ òtítọ́ nítorí kò sí òtítọ́ ninu rẹ̀. Nígbà tí ó bá sọ̀rọ̀, irọ́ ni ó ń pa. Ọ̀rọ̀ ti ara rẹ̀ ní ń sọ. Òpùrọ́ ni, òun sì ni baba irọ́.


Irú rẹ̀ kì í ṣe nǹkan ìjọjú, nítorí Satani pàápàá a máa farahàn bí angẹli ìmọ́lẹ̀.


Nígbà náà ẹ̀ ń hùwà gẹ́gẹ́ bí ẹni ti ayé yìí, ẹ̀ ń gbọ́ràn sí aláṣẹ àwọn ẹ̀mí tí ó wà ninu òfuurufú lẹ́nu, àwọn ẹ̀mí wọnyi ń ṣiṣẹ́ títí di ìsinsìnyìí ninu àwọn ọmọ tí kò gbọ́ràn sí Ọlọrun lẹ́nu.


Nítorí, “Gbogbo ẹlẹ́ran-ara dàbí Koríko, gbogbo ògo rẹ̀ dàbí òdòdó. Koríko a máa gbẹ, òdòdó a máa rẹ̀,


A mọ̀ pé láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni a ti wá, ati pé gbogbo ayé patapata wà lábẹ́ Èṣù.


Wọ́n lé Ẹranko Ewèlè náà jáde–ejò àtijọ́ nì tí à ń pè ní Èṣù, tabi Satani tí ó ń tan àwọn tí ó ń gbé inú ayé jẹ. Wọ́n lé e jáde lọ sinu ayé, ati òun ati àwọn angẹli rẹ̀.


Ẹranko náà tí mo rí dàbí àmọ̀tẹ́kùn. Ẹsẹ̀ rẹ̀ dàbí ti ìkookò. Ẹnu rẹ̀ dàbí ti kinniun. Ẹranko Ewèlè náà fún un ní agbára rẹ̀, ati ìtẹ́ rẹ̀ ati àṣẹ ńlá rẹ̀.


A fún un ní agbára láti gbógun ti àwọn eniyan Ọlọrun ati láti ṣẹgun wọn. A tún fún un ní àṣẹ lórí gbogbo ẹ̀yà ati orílẹ̀-èdè ati oríṣìíríṣìí èdè ati gbogbo eniyan.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan