Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 3:5 - Yoruba Bible

5 Gbogbo ọ̀gbun ni yóo jẹ́ dídí gbogbo òkè gíga ati òkè kéékèèké ni yóo jẹ́ rírẹ̀ sílẹ̀. A óo tọ́ ibi tí ó bá ṣe kọ́rọ-kọ̀rọ, a óo sì sọ ọ̀nà tí kò bá dán tẹ́lẹ̀ di dídán

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

5 Gbogbo ọgbún li a o kún, gbogbo òke nla ati òke kekere li a o tẹ-bẹrẹ; wíwọ li a o ṣe ni títọ, ati ọ̀na palapala li a o sọ di kikuna;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 Gbogbo ọ̀gbun ni a yóò kún, gbogbo òkè ńlá àti òkè kékeré ni a ó tẹ́ pẹẹrẹ; Wíwọ́ ni a ó ṣe ní títọ́, àti ọ̀nà gbọ́ngungbọ̀ngun ni a o sọ di dídán.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 3:5
11 Iomraidhean Croise  

Gbogbo àfonífojì ni a óo ru sókè, a óo sì sọ àwọn òkè ńlá ati òkè kéékèèké di pẹ̀tẹ́lẹ̀: Gbogbo ọ̀nà tí ó wọ́ ni yóo di títọ́, ọ̀nà gbágun-gbàgun yóo sì di títẹ́jú.


“N óo darí àwọn afọ́jú, n óo mú wọn gba ọ̀nà tí wọn kò mọ̀ rí, n óo tọ́ wọn sọ́nà, ní ọ̀nà tí wọn kò mọ̀ rí. N óo sọ òkùnkùn di ìmọ́lẹ̀ níwájú wọn, n óo sì sọ àwọn ibi tí ó rí pálapàla di títẹ́jú. N óo ṣe àwọn nǹkan, n kò sì ní kọ̀ wọ́n sílẹ̀.


OLUWA ní, “N óo lọ ṣáájú rẹ, n óo sọ àwọn òkè ńlá di pẹ̀tẹ́lẹ̀; n óo fọ́ ìlẹ̀kùn idẹ, n óo sì gé ọ̀pá ìlẹ̀kùn irin.


“N óo sọ gbogbo òkè mi di ojú ọ̀nà, n óo kún gbogbo òpópó ọ̀nà mi.


Gbogbo igi inú igbó yóo mọ̀ pé èmi, OLUWA, ni èmi í sọ igi ńlá di kékeré, mà sì máa sọ igi kékeré di ńlá. Mà máa sọ igi tútù di gbígbẹ, má sì máa mú kí igi gbígbẹ pada rúwé. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni n óo sì ṣe.”


Kí arakunrin tí ó jẹ́ mẹ̀kúnnù kí ó yọ̀ nígbà tí Ọlọrun bá gbé e ga.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan