Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 3:3 - Yoruba Bible

3 Ó bá ń kiri gbogbo ìgbèríko odò Jọdani, ó ń waasu pé kí àwọn eniyan ronupiwada, kí wọ́n ṣe ìrìbọmi, kí Ọlọrun lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì wọ́n.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 O si wá si gbogbo ilẹ ìha Jordani, o nwasu baptismu ironupiwada fun imukuro ẹ̀ṣẹ;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Ó sì wá sí gbogbo ilẹ̀ aginjù Jordani, ó ń wàásù ìtẹ̀bọmi ìrònúpìwàdà fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 3:3
12 Iomraidhean Croise  

Ìrìbọmi ni èmi fi ń wẹ̀ yín mọ́ nítorí ìrònúpìwàdà. Ṣugbọn ẹni tí ó ń bọ̀ lẹ́yìn mi jù mí lọ; èmi kò tó ẹni tí ó lè kó bàtà rẹ̀. Ẹ̀mí Mímọ́ ati iná ni òun yóo fi wẹ̀ yín mọ́.


ọpọlọpọ àwọn ọmọ Israẹli ni yóo sì yipada sí Oluwa Ọlọrun wọn.


láti fi ìmọ̀ ìgbàlà fún àwọn eniyan rẹ̀, nípa ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ wọn,


Jesu pada láti odò Jọdani, ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́. Ẹ̀mí bá darí rẹ̀ lọ sí aṣálẹ̀.


Ní Bẹtani tí ó wà ní apá ìlà oòrùn odò Jọdani ni nǹkan wọnyi ti ṣẹlẹ̀, níbi tí Johanu ti ń ṣe ìrìbọmi.


Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà bá lọ sọ́dọ̀ Johanu, wọ́n wí fún un pé, “Olùkọ́ni, ọkunrin tí ó wà pẹlu rẹ ní òdìkejì odò Jọdani, tí o jẹ́rìí nípa rẹ̀, ń ṣe ìrìbọmi, gbogbo eniyan sì ń tọ̀ ọ́ lọ.”


Kí Jesu tó yọjú, Johanu ti ń waasu fún gbogbo àwọn eniyan Israẹli pé kí wọ́n ṣe ìrìbọmi bí àmì pé wọ́n ronupiwada.


Paulu bá sọ pé, “Ìrìbọmi pé a ronupiwada ni Johanu ṣe. Ó ń sọ fún àwọn eniyan pé kí wọ́n gba ẹni tí ó ń bọ̀ lẹ́yìn òun gbọ́. Ẹni náà ni Jesu.”


Ó wá bèèrè pé, kí ni mo tún ń fẹ́ nisinsinyii? Ó ní kí n dìde, kí n ṣe ìrìbọmi, kí n wẹ ẹ̀ṣẹ̀ mi nù, kí n pe orúkọ Oluwa.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan