Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 3:11 - Yoruba Bible

11 Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹni tí ó bá ní dàńṣíkí meji, kí ó fún ẹni tí kò ní lọ́kan. Ẹni tí ó bá ní oúnjẹ níláti ṣe bákan náà.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

11 O dahùn o si wi fun wọn pe, Ẹniti o ba li ẹ̀wu meji, ki o fi ọkan fun ẹniti kò ni; ẹniti o ba si li onjẹ, ki o ṣe bẹ̃ pẹlu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

11 Ó dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ẹni tí ó bá ní ẹ̀wù méjì, kí ó fi ọ̀kan fún ẹni tí kò ní; ẹni tí ó bá sì ní oúnjẹ, kí ó ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 3:11
22 Iomraidhean Croise  

tí kò ni ẹnikẹ́ni lára, ṣugbọn tí ó dá ohun tí onígbèsè fi ṣe ìdúró pada fún un; tí kò fi ipá jalè, tí ó ń fún ẹni tí ebi ń pa ní oúnjẹ, tí ó sì ń da aṣọ bo ẹni tí ó wà ní ìhòòhò,


Nítorí náà, kabiyesi, gba ìmọ̀ràn tí n óo fún ọ yìí; jáwọ́ ninu ẹ̀ṣẹ̀, sì máa ṣe òdodo, jáwọ́ ninu ìwà ìkà, máa ṣàánú fún àwọn tí a ni lára, bóyá èyí lè mú kí àkókò alaafia rẹ gùn sí i.”


Ọba yóo wá dá wọn lóhùn pé, ‘Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, níwọ̀n ìgbà tí ẹ ti ṣe é fún ọ̀kan ninu àwọn arakunrin mi tí ó kéré jùlọ, èmi ni ẹ ṣe é fún.’


Ohun kan ni kí ẹ ṣe: ẹ fi àwọn ohun tí ó wà ninu kọ́ọ̀bù ati àwo ṣe ìtọrẹ àánú; bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, gbogbo nǹkan di mímọ́ fun yín.


Nígbà tí Jesu gbọ́, ó sọ fún un pé, “Nǹkankan ló kù ọ́ kù. Lọ ta gbogbo ohun tí o ní, kí o pín owó rẹ̀ fún àwọn talaka, ìwọ yóo wá ní ìṣúra ní ọ̀run. Kí o máa wá tọ̀ mí lẹ́yìn.”


Sakiu bá dìde dúró, ó sọ fún Oluwa pé, “N óo pín ààbọ̀ ohun tí mo ní fún àwọn talaka. Bí mo bá sì ti fi ọ̀nà èrú gba ohunkohun lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, mo ṣetán láti dá a pada ní ìlọ́po mẹrin.”


Nígbà tí ó jẹ́ pé Judasi ni akápò, àwọn mìíràn ń rò pé ohun tí Jesu sọ fún un ni pé, “Lọ ra àwọn ohun tí a óo lò fún Àjọ̀dún Ìrékọjá, tabi ohun tí a óo fún àwọn talaka.”


Olùfọkànsìn ni. Òun ati gbogbo ìdílé rẹ̀ sì bẹ̀rù Ọlọrun. A máa ṣàánú àwọn eniyan lọpọlọpọ, a sì máa gbadura sí Ọlọrun nígbà gbogbo.


Ó ní, ‘Kọniliu, Ọlọrun ti gbọ́ adura rẹ, ó sì ti ranti iṣẹ́ àánú rẹ.


Kọniliu bá tẹjú mọ́ ọn. Ẹ̀rù bà á, ó ní, “Kí ló dé, alàgbà?” Angẹli yìí bá sọ fún un pé, “Adura rẹ ti gbà; iṣẹ́ àánú rẹ ti gòkè lọ siwaju Ọlọrun. Ọlọrun sì ti ranti rẹ.


Kí ẹni tí ń jalè má jalè mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀ kí ó kúkú gbìyànjú láti fi ọwọ́ ara rẹ̀ ṣe iṣẹ́ rere, kí òun náà lè ní ohun tí yóo fún àwọn aláìní.


Mo pa á láṣẹ fún àwọn ọlọ́rọ̀ ayé yìí, pé kí wọ́n má ṣe ní ọkàn gíga. Bẹ́ẹ̀ ni kí wọ́n má ṣe gbára lé ọrọ̀ tí kò lágbẹkẹ̀lé, ṣugbọn kí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun tí ó ń fún wa ní gbogbo ọrọ̀ fún ìgbádùn wa.


Kí wọn máa ṣe rere, kí wọn jẹ́ ọlọ́rọ̀ ninu iṣẹ́ rere, kí wọn fẹ́ràn láti máa ṣe ọrẹ ati láti máa mú ninu ohun ìní wọn fún àwọn ẹlòmíràn,


Nítorí Ọlọrun kì í ṣe alaiṣootọ, tí yóo fi gbàgbé iṣẹ́ yín ati ìfẹ́ yín tí ẹ fihàn sí orúkọ rẹ̀, nígbà tí ẹ ṣe iṣẹ́ iranṣẹ fún àwọn onigbagbọ, bí ẹ ti tún ń ṣe nisinsinyii.


Ẹ̀sìn tí ó pé, tí kò lábàwọ́n níwájú Ọlọrun Baba ni pé kí eniyan máa ran àwọn ọmọ tí kò ní òbí ati àwọn opó lọ́wọ́ ninu ipò ìbànújẹ́ wọn, kí eniyan sì pa ara rẹ̀ mọ́ láìléèérí ninu ayé.


Ẹ̀yin ará mi, èrè kí ni ó jẹ́, tí ẹnìkan bá sọ pé òun ní igbagbọ, ṣugbọn tí igbagbọ yìí kò hàn ninu iṣẹ́ rẹ̀? Ṣé igbagbọ yìí lè gbà á là?


Bí ẹnìkan bá ní dúkìá ayé yìí, tí ó rí arakunrin rẹ̀ tí ó ṣe aláìní, tí kò ṣàánú rẹ̀, a ṣe lè wí pé ìfẹ́ Ọlọrun ń gbé inú irú ẹni bẹ́ẹ̀?


Bí ẹnikẹ́ni bá wí pé, òun fẹ́ràn Ọlọrun, tí ó bá kórìíra arakunrin rẹ̀, èké ni. Nítorí ẹni tí kò bá fẹ́ràn arakunrin rẹ̀ tí ó ń fojú rí, kò lè fẹ́ràn Ọlọrun tí kò rí.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan