Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 3:1 - Yoruba Bible

1 Ní ọdún kẹẹdogun tí Ọba Tiberiu ti wà lórí oyè, nígbà tí Pọntiu Pilatu jẹ́ gomina Judia, tí Hẹrọdu jẹ́ baálẹ̀ Galili, tí Filipi arakunrin rẹ̀ jẹ́ baálẹ̀ Ituria ati ti agbègbè Tirakoniti, Lusaniu jẹ́ baálẹ̀ Abilene;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 LI ọdún kẹdogun ijọba Tiberiu Kesari, nigbati Pontiu Pilatu jẹ Bãlẹ, Judea, ti Herodu si jẹ tetrarki Galili, Filippi arakunrin rẹ̀ si jẹ tetrarki Iturea ati ti Trakoniti, Lisania si jẹ tetrarki Abilene,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Ní ọdún kẹ́ẹ̀dógún ìjọba Tiberiu Kesari, nígbà tí Pọntiu Pilatu jẹ́ baálẹ̀ Judea, tí Herodu sì jẹ́ tetrarki Galili, Filipi arákùnrin rẹ̀ sì jẹ́ tetrarki Iturea àti ti Trakoniti, Lisania sì jẹ́ tetrarki Abilene,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 3:1
19 Iomraidhean Croise  

Ọ̀pá àṣẹ ọba kì yóo kúrò ní ilé Juda, arọmọdọmọ rẹ̀ ni yóo sì máa jọba, títí tí yóo fi dé ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ni ín; gbogbo ìran eniyan ni yóo sì máa pa àṣẹ rẹ̀ mọ́.


Ní àkókò náà, Hẹrọdu ọba gbúròó Jesu.


Nítorí Hẹrọdu yìí ni ó ti pàṣẹ pé kí wọ́n mú Johanu, kí wọ́n dè é, kí wọ́n sì fi í sẹ́wọ̀n nítorí ọ̀rọ̀ Hẹrọdiasi, iyawo Filipi, arakunrin Hẹrọdu.


Nígbà tí Hẹrọdu ń ṣe ọjọ́ ìbí rẹ̀, ọdọmọbinrin Hẹrọdiasi bẹ̀rẹ̀ sí jó lójú agbo. Èyí dùn mọ́ Hẹrọdu ninu


Nítorí náà sọ ohun tí o rò fún wa. Ó tọ̀nà láti san owó-orí fún Kesari ni, àbí kò tọ̀nà?”


Wọ́n dè é, wọ́n bá fà á lọ láti fi lé Pilatu, gomina, lọ́wọ́.


Nítorí Hẹrọdu kan náà yìí ni ó ranṣẹ lọ mú Johanu tí ó fi í sẹ́wọ̀n nítorí ọ̀ràn Hẹrọdiasi iyawo Filipi arakunrin Hẹrọdu tí Hẹrọdu gbà.


Nígbà tí ó di ọjọ́ kan, Hẹrọdiasi rí àkókò tí ó wọ̀ láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Hẹrọdu se àsè ọjọ́ ìbí rẹ̀, ó pe àwọn ìjòyè, àwọn ọ̀gágun, ati àwọn eniyan pataki ilẹ̀ Galili.


Ní àkókò náà, àwọn Farisi kan wá sọ́dọ̀ Jesu, wọ́n sọ fún un pé, “Kúrò níhìn-ín nítorí Hẹrọdu fẹ́ pa ọ́.”


Ní àkókò náà, àṣẹ kan jáde láti ọ̀dọ̀ Kesari Augustu pé kí gbogbo ayé lọ kọ orúkọ wọn sinu ìwé ìjọba.


Pilatu bá gbà láti ṣe bí wọ́n ti fẹ́.


Ní àkókò kan, Johanu bá Hẹrọdu baálẹ̀ wí nítorí ọ̀ràn Hẹrọdiasi, iyawo Filipi, arakunrin rẹ̀, tí Hẹrọdu gbà. Ó tún bá a wí fún gbogbo nǹkan burúkú mìíràn tí ó ṣe.


Nígbà tó yá, Hẹrọdu, baálẹ̀, gbọ́ nípa gbogbo nǹkan tí ó ṣẹlẹ̀, ó dààmú; nítorí àwọn kan ń sọ pé Johanu ni ó jí dìde kúrò ninu òkú.


“Gomina ọlọ́lá jùlọ, Fẹliksi, èmi Kilaudiu Lisia ki yín.


Lẹ́yìn ọdún meji Pọkiu Fẹstu gba ipò Fẹliksi. Nítorí Fẹliksi ń wá ojurere àwọn Juu, ó fi Paulu sílẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n.


Agiripa bá dìde pẹlu gomina ati Berenike ati gbogbo àwọn tí ó jókòó pẹlu wọn.


Nítorí òdodo ni pé Hẹrọdu ati Pọntiu Pilatu pẹlu àwọn tí kì í ṣe Juu ati àwọn eniyan Israẹli péjọpọ̀ ní ìlú yìí, wọ́n ṣe ohun tí ó lòdì sí ọmọ mímọ́ rẹ, Jesu tí o ti fi òróró yàn ní Mesaya,


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan