Luku 23:2 - Yoruba Bible2 Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí fi ẹ̀sùn kàn án pé, “A rí i pé ńṣe ni ọkunrin yìí ń ba ìlú jẹ́. Ó ní kí àwọn eniyan má san owó-orí. Ó tún pe ara rẹ̀ ní Mesaya, Ọba.” Faic an caibideilBibeli Mimọ2 Nwọn si bẹ̀rẹ si ifi i sùn, wipe, Awa ri ọkunrin yi o nyi orilẹ-ede wa li ọkàn pada, o si nda wọn lẹkun lati san owode fun Kesari, o nwipe on tikara-on ni Kristi ọba. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní2 Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ẹ̀sùn kàn án, wí pé, “Àwa rí ọkùnrin yìí ó ń yí orílẹ̀-èdè wa lọ́kàn padà, ó sì ń dá wọn lẹ́kun láti san owó òde fún Kesari, ó ń wí pé, òun tìkára òun ni Kristi ọba.” Faic an caibideil |