Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 21:1 - Yoruba Bible

1 Bí Jesu ti gbé ojú sókè ó rí àwọn ọlọ́rọ̀ bí wọ́n ti ń dá owó ọrẹ wọn sinu àpótí ìṣúra.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 NIGBATI o si gbé oju soke, o ri awọn ọlọrọ̀ nfi ẹ̀bun wọn sinu apoti iṣura.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Nígbà tí ó sì gbé ojú sókè, ó rí àwọn ọlọ́rọ̀ ń fi ẹ̀bùn wọn sínú àpótí ìṣúra.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 21:1
12 Iomraidhean Croise  

Ó kó gbogbo ìṣúra tí ó wà ninu ilé OLUWA ati ti ààfin ọba pátá; gbogbo apata wúrà tí Solomoni ṣe ni ó kó lọ pẹlu.


Nígbà náà ni Jehoiada gbé àpótí kan, ó lu ihò sí orí rẹ̀, ó gbé e sí ẹ̀bá pẹpẹ ìrúbọ ní ọwọ́ ọ̀tún tí eniyan bá wọ ilé OLUWA. Gbogbo àwọn alufaa tí wọ́n bá ṣiṣẹ́ ninu ilé OLUWA a sì máa kó owó tí àwọn eniyan bá mú wá sinu rẹ̀.


Ó kó gbogbo àwọn ìṣúra ilé OLUWA ati àwọn ìṣúra tí ó wà ní ààfin. Gbogbo ohun èèlò wúrà tí wọ́n wà ninu ilé OLUWA, tí Solomoni ọba Israẹli ṣe, ni ó gé sí wẹ́wẹ́, gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti sọ tẹ́lẹ̀.


Ọba Babiloni kó gbogbo ohun èlò ilé OLUWA, ati ńláńlá, ati kéékèèké, ati àwọn ìṣúra tí ó wà níbẹ̀, ati àwọn tí wọ́n wà ní ààfin ati ti ilé àwọn ìjòyè; ó kó gbogbo wọn patapata lọ sí Babiloni.


Mo bá yan àwọn kan tí yóo máa mójútó ètò ìsúná owó ní àwọn ilé ìṣúra. Àwọn ni: Ṣelemaya, alufaa, Sadoku, akọ̀wé, ati Pedaaya, ọmọ Lefi. Ẹni tí ó jẹ́ igbákejì wọn ni Hanani ọmọ Sakuri, ọmọ Matanaya, nítorí pé wọ́n mọ̀ wọ́n sí olóòótọ́, iṣẹ́ wọn sì ni láti fún àwọn arakunrin wọn ní ẹ̀tọ́ wọn.


Àwọn olórí alufaa mú owó fadaka náà, wọ́n ní, “Kò tọ́ fún wa láti fi í sinu àpò ìṣúra Tẹmpili mọ́ nítorí owó ẹ̀jẹ̀ ni.”


Wọn a máa jẹ ilé àwọn opó run. Wọ́n a máa gba adura gígùn láti ṣe àṣehàn. Wọn yóo gba ìdájọ́ líle.”


Jesu wí báyìí nígbà tí ó ń kọ́ àwọn eniyan ninu Tẹmpili ninu iyàrá ìṣúra. Ẹnikẹ́ni kò mú un, nítorí àkókò rẹ̀ kò ì tíì tó.


Ṣugbọn gbogbo fadaka ati wúrà ati àwọn ohun èlò idẹ ati ti irin jẹ́ ohun ìyàsọ́tọ̀ fún OLUWA, inú ilé ìṣúra OLUWA ni a óo kó wọn sí.”


Wọ́n dáná sun ìlú náà ati gbogbo nǹkan tí ó wà ninu rẹ̀, àfi fadaka ati wúrà, ati àwọn ohun èlò idẹ, ati ti irin, ni wọ́n kó lọ sinu ilé ìṣúra OLUWA.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan