Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 20:1 - Yoruba Bible

1 Ní ọjọ́ kan, bí Jesu ti ń kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́ ninu Tẹmpili, tí ó ń waasu ìyìn rere fún wọn, àwọn olórí alufaa, àwọn amòfin, ati àwọn àgbà wá sọ́dọ̀ rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 O si ṣe, ni ijọ kan li ọjọ wọnni, bi o ti nkọ́ awọn enia ni tẹmpili ti o si nwasu ihinrere, awọn olori alufa, ati awọn pẹlu awọn agbagbà dide sí i,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Ní ọjọ́ kan, bí ó ti ń kọ́ àwọn ènìyàn ní tẹmpili tí ó sì ń wàásù ìhìnrere, àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn akọ̀wé, pẹ̀lú àwọn àgbàgbà dìde sí i.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 20:1
10 Iomraidhean Croise  

Jesu bá sọ fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ jáde wá mú mi pẹlu idà ati kùmọ̀ bí ìgbà tí ẹ wá mú olè. Ojoojumọ ni mò ń jókòó ninu Tẹmpili láti kọ́ àwọn eniyan. Ẹ kò mú mi nígbà náà!


Wọ́n bi í pé, “Sọ fún wa irú àṣẹ tí o fi ń ṣe àwọn nǹkan wọnyi; ta ni ó sì fún ọ ní àṣẹ yìí?”


Lẹ́yìn èyí, Jesu ń rìn káàkiri láti ìlú dé ìlú, ati láti abúlé dé abúlé. Ó ń waasu ìyìn rere ìjọba Ọlọrun. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila ń bá a kiri.


Jesu dá a lóhùn pé, “Ní gbangba ni èmi tí máa ń bá aráyé sọ̀rọ̀. Ninu ilé ìpàdé ati ninu Tẹmpili ni èmi tí máa ń kọ́ àwọn eniyan nígbà gbogbo, níbi tí gbogbo àwọn Juu ń péjọ sí, n kò sọ ohunkohun níkọ̀kọ̀.


Bí Peteru ti ń bá àwọn eniyan sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, Johanu wà lọ́dọ̀ rẹ̀, àwọn alufaa ati olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ Tẹmpili ati àwọn Sadusi bá dé.


Wọ́n rú àwọn eniyan ati àwọn àgbààgbà ati àwọn amòfin nídìí, ni wọ́n bá mú un, wọ́n fà á lọ siwaju àwọn ìgbìmọ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan