Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 2:9 - Yoruba Bible

9 Angẹli Oluwa kan bá yọ sí wọn, ògo Oluwa tan ìmọ́lẹ̀ yí wọn ká. Ẹ̀rù bà wọ́n gan-an.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

9 Sá si kiyesi i, angẹli Oluwa na yọ si wọn, ogo Oluwa si ràn yi wọn ká: ẹ̀ru si ba wọn gidigidi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 Angẹli Olúwa sì yọ sí wọn, ògo Olúwa sì ràn yí wọn ká: ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 2:9
27 Iomraidhean Croise  

tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn alufaa kò lè dúró láti ṣe iṣẹ́ ìsìn, nítorí ògo OLUWA kún inú ilé OLUWA.


Bí Aaroni ti ń bá gbogbo ìjọ eniyan Israẹli sọ̀rọ̀, wọ́n wo apá aṣálẹ̀, wọ́n sì rí i pé ògo OLUWA hàn ninu ìkùukùu.


Nígbà tí ó bá di òwúrọ̀ ọ̀la, ẹ óo rí ògo OLUWA, nítorí ó ti gbọ́ kíkùn tí ẹ̀ ń kùn sí i. Kí ni àwa yìí jẹ́, tí ẹ óo fi máa kùn sí wa?”


Nítòótọ́ yóo tanná bí òdòdó, yóo yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, yóo sì kọrin. Ògo Lẹbanoni yóo di tìrẹ ati iyì Kamẹli ati ti Ṣaroni. Wọn óo rí ògo OLUWA, wọn óo rí ọlá ńlá Ọlọrun wa.


Ògo OLUWA yóo farahàn, gbogbo eniyan yóo sì jọ fojú rí i. OLUWA ni ó fi ẹnu ara rẹ̀ sọ bẹ́ẹ̀.”


Dìde, tan ìmọ́lẹ̀; nítorí ìmọ́lẹ̀ rẹ ti dé, ògo OLUWA sì ti tàn sára rẹ.


Mo bá dìde, mo jáde lọ sí àfonífojì. Mo rí ìfarahàn ògo OLUWA níbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí mo ti rí i lẹ́bàá odò Kebari, mo bá dojúbolẹ̀.


Bí ó ti ń ronú bí yóo ti gbé ọ̀rọ̀ náà gbà, angẹli Oluwa kan fara hàn án lójú àlá. Ó sọ fún un pé, “Josẹfu, ọmọ Dafidi, má bẹ̀rù láti mú Maria aya rẹ sọ́dọ̀, nítorí láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ ni oyún tí ó ní.


Angẹli náà wọlé tọ Maria lọ, ó kí i, ó ní “Alaafia ni fún ọ! Ìwọ ẹni tí Ọlọrun kọjú sí ṣe ní oore, Oluwa wà pẹlu rẹ.”


Ní àkókò náà, àwọn olùṣọ́-aguntan wà ní pápá, níbi tí wọn ń ṣọ́ aguntan wọn ní òru.


Bí wọ́n ti dúró tí wọn kò mọ ohun tí wọn yóo ṣe, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkunrin meji kan bá yọ sí wọn, wọ́n wọ aṣọ dídán.


Aisaya sọ nǹkan wọnyi nítorí ó rí ògo Jesu, ó wá sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀.


Angẹli Oluwa kan bá yọ dé, ìmọ́lẹ̀ sì tàn ninu ilé náà. Angẹli náà bá rọra lu Peteru lẹ́gbẹ̀ẹ́, ó jí i, ó ní, “Dìde kíá.” Àwọn ẹ̀wọ̀n tí wọ́n fi de Peteru bá yọ bọ́ kúrò ní ọwọ́ rẹ̀,


Nítorí ní alẹ́ àná, angẹli Ọlọrun mi, tí mò ń sìn dúró tì mí, ó ní,


Nígbà tí ó di òru, angẹli Oluwa ṣí ìlẹ̀kùn ilé-ẹ̀wọ̀n, ó sìn wọ́n jáde, ó sọ fún wọn pé,


Kò sí aṣọ tí ó bò wá lójú. Ojú gbogbo wa ń fi ògo Oluwa hàn bí ìgbà tí eniyan ń wo ojú rẹ̀ ninu dígí. À ń pa wá dà sí ògo mìíràn tí ó tayọ ti àkọ́kọ́. Èyí jẹ́ iṣẹ́ Oluwa tí í ṣe Ẹ̀mí.


Nítorí Ọlọrun tí ó ní kí ìmọ́lẹ̀ tàn láti inú òkùnkùn, òun ni ó tan ìmọ́lẹ̀ sí ọkàn wa, kí ìmọ́lẹ̀ ìmọ̀ ògo Ọlọrun lè tàn sí wa ní ojú Kristi.


Kò sí ẹni tí kò mọ̀ pé àṣírí ẹ̀sìn wa jinlẹ̀ pupọ: Ẹni tí ó farahàn ninu ẹran-ara, tí a dá láre ninu ẹ̀mí, tí àwọn angẹli fi ojú rí, tí à ń waasu rẹ̀ láàrin àwọn alaigbagbọ, tí a gbàgbọ́ ninu ayé, tí a gbé lọ sinu ògo.


Ohun tí wọ́n rí bani lẹ́rù tóbẹ́ẹ̀ tí Mose fi sọ pé, “Ẹ̀rù ń bà mí! Gbígbọ̀n ni gbogbo ara mi ń gbọ̀n látòkè délẹ̀.”


Lẹ́yìn èyí mo tún rí angẹli tí ó ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ bọ̀. Ó ní àṣẹ ńlá. Gbogbo ayé mọ́lẹ̀ nítorí ẹwà ògo rẹ̀.


Mo wá rí ìtẹ́ funfun ńlá kan ati ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀. Ayé ati ọ̀run sálọ fún un, a kò rí ààyè fún wọn mọ́.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan