Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 2:7 - Yoruba Bible

7 Ó bá bí àkọ́bí rẹ̀ ọmọkunrin, ó fi ọ̀já wé e, ó tẹ́ ẹ sí ibùjẹ ẹran, nítorí kò sí àyè fún wọn ninu ilé èrò.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

7 O si bí akọbi rẹ̀ ọmọkunrin, o si fi ọja wé e, o si tẹ́ ẹ sinu ibujẹ ẹran; nitoriti àye kò si fun wọn ninu ile èro.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Ó sì bí àkọ́bí rẹ̀ ọmọkùnrin, ó sì fi ọ̀já wé e, ó sì tẹ́ ẹ sínú ibùjẹ ẹran; nítorí tí ààyè kò sí fún wọn nínú ilé èrò.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 2:7
16 Iomraidhean Croise  

Nígbà tí wọ́n dé ibi tí wọn yóo sùn lálẹ́ ọjọ́ náà, ọ̀kan ninu wọn tú àpò rẹ̀ láti fún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní oúnjẹ, ó bá rí owó rẹ̀ tí wọ́n dì sí ẹnu àpò rẹ̀.


Nígbà tí à ń pada lọ tí a dé ibi tí a fẹ́ sùn, a tú àpò wa, olukuluku wa bá owó tirẹ̀ lẹ́nu àpò rẹ̀, kò sí ti ẹni tí ó dín rárá, a mú owó náà lọ́wọ́ báyìí.


Ṣugbọn kòkòrò lásán ni mí, n kì í ṣe eniyan; ayé kẹ́gàn mi, gbogbo eniyan sì ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà.


Nígbà tí wọ́n dé ilé èrò kan ní ojú ọ̀nà Ijipti, OLUWA pàdé Mose, ó sì fẹ́ pa á.


Nítorí náà, OLUWA fúnrarẹ̀ yóo fun yín ní àmì kan. Ẹ gbọ́! Ọlọ́mọge kan yóo lóyún yóo sì bí ọmọkunrin kan, yóo pe orúkọ rẹ̀ ní Imanuẹli.


Kò sì bá a lòpọ̀ rárá títí ó fi bímọ. Ó sì pe orúkọ ọmọ náà ní Jesu.


Àbí ọmọ gbẹ́nà-gbẹ́nà yẹn kọ́ ni? Tí orúkọ ìyá rẹ̀ ń jẹ́ Maria, tí àwọn arakunrin rẹ̀ ń jẹ́ Jakọbu ati Josẹfu ati Simoni ati Judasi?


Jesu wí fún un pé, “Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ihò, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ní ìtẹ́; ṣugbọn Ọmọ-Eniyan kò ní ibi tí yóo gbé orí rẹ̀ lé.”


Ó bá lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó fi òróró ati ọtí waini sí ojú ọgbẹ́ rẹ̀, ó sì fi aṣọ wé e. Ó gbé ọkunrin náà ka orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ tí ó gùn. Ó gbé e lọ sí ilé èrò níbi tí ó ti ṣe ìtọ́jú rẹ̀.


Ó wá yá nígbà tí wọ́n wà ní Bẹtilẹhẹmu, àkókò tó fún Maria láti bímọ.


Ní àkókò náà, àwọn olùṣọ́-aguntan wà ní pápá, níbi tí wọn ń ṣọ́ aguntan wọn ní òru.


Ọ̀rọ̀ náà wá di eniyan, ó ń gbé ààrin wa, a rí ògo rẹ̀, ògo bíi ti Ọmọ bíbí kan ṣoṣo tí ó ti ọ̀dọ̀ Baba wá, tí ó kún fún oore-ọ̀fẹ́ ati òtítọ́.


Nítorí ẹ mọ oore-ọ̀fẹ́ Oluwa wa Jesu Kristi, pé nítorí tiwa, òun tí ó jẹ́ ọlọ́rọ̀ di aláìní, kí ẹ lè di ọlọ́rọ̀ nípa àìní tirẹ̀.


Ṣugbọn nígbà tí ó tó àkókò tí ó wọ̀, Ọlọrun rán Ọmọ rẹ̀ wá. Obinrin ni ó bí i, ó bí i lábẹ́ òfin àwọn Juu,


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan