Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 2:4 - Yoruba Bible

4 Josẹfu náà gbéra láti Nasarẹti ìlú kan ní ilẹ̀ Galili, ó lọ sí ìlú Dafidi tí ó ń jẹ́ Bẹtilẹhẹmu, ní ilẹ̀ Judia, nítorí ẹbí Dafidi ni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

4 Josefu pẹlu si goke lati Nasareti ilu Galili lọ, si ilu Dafidi ni Judea, ti a npè ni Betlehemu; nitoriti iran ati idile Dafidi ni iṣe,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Josẹfu pẹ̀lú sì gòkè láti Nasareti ni Galili, sí ìlú Dafidi ní Judea, tí à ń pè ní Bẹtilẹhẹmu; nítorí ti ìran àti ìdílé Dafidi ní í ṣe,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 2:4
24 Iomraidhean Croise  

Bẹ́ẹ̀ ni Rakẹli ṣe kú, wọ́n sì sin ín sí ẹ̀bá ọ̀nà Efurati, èyí nnì ni Bẹtilẹhẹmu.


Ìbànújẹ́ ni ó jẹ́ fún mi pé nígbà tí mò ń ti Padani-aramu bọ̀, Rakẹli kú lọ́nà, ní ilẹ̀ Kenaani, ibi tí ó dákẹ́ sí kò jìnnà pupọ sí Efurati. Lójú ọ̀nà Efurati náà ni mo sì sin ín sí.” (Efurati yìí ni wọ́n ń pè ní Bẹtilẹhẹmu.)


OLUWA ní, “Ṣugbọn, ìwọ Bẹtilẹhẹmu ní Efurata, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o kéré láàrin gbogbo ẹ̀yà Juda, sibẹ láti inú rẹ ni ẹni tí yóo jẹ́ aláṣẹ Israẹli yóo ti jáde wá fún mi, ẹni tí ìran tí ó ti ṣẹ̀ jẹ́ ti ayérayé, tí ó ti wà láti ìgbà laelae.”


Bí ó ti ń ronú bí yóo ti gbé ọ̀rọ̀ náà gbà, angẹli Oluwa kan fara hàn án lójú àlá. Ó sọ fún un pé, “Josẹfu, ọmọ Dafidi, má bẹ̀rù láti mú Maria aya rẹ sọ́dọ̀, nítorí láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ ni oyún tí ó ní.


Ó bá ń gbé ìlú kan tí à ń pé ní Nasarẹti. Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí ọ̀rọ̀ tí àwọn wolii sọ lè ṣẹ pé, “A óo pè é ní ará Nasarẹti.”


Gbogbo àwọn eniyan bá lọ kọ orúkọ wọn sílẹ̀, ẹnìkọ̀ọ̀kan lọ sí ìlú ara rẹ̀.


Ó lọ kọ orúkọ sílẹ̀ pẹlu Maria iyawo àfẹ́sọ́nà rẹ̀, tí ó lóyún, tí ó sì fẹ́rẹ̀ bímọ.


Ó wá dé Nasarẹti, ìlú tí wọ́n ti tọ́ ọ dàgbà. Gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀, nígbà tí ó di ọjọ́ ìsinmi, ó lọ sí ilé ìpàdé. Ó bá dìde láti ka Ìwé Mímọ́.


Nataniẹli bi í pé, “Ṣé nǹkan rere kan lè ti Nasarẹti wá?” Filipi dá a lóhùn pé, “Wá wò ó.”


Ṣebí Ìwé Mímọ́ ti sọ pé láti inú ìdílé Dafidi, ní Bẹtilẹhẹmu ìlú Dafidi, ni Mesaya yóo ti wá?”


Àwọn mejeeji bá bẹ̀rẹ̀ sí lọ títí wọ́n fi dé Bẹtilẹhẹmu. Nígbà tí wọ́n wọ Bẹtilẹhẹmu, gbogbo ìlú mì tìtì nítorí wọn. Àwọn obinrin bá bẹ̀rẹ̀ sí bèèrè pé, “Ṣé Naomi nìyí?”


Kò pẹ́ pupọ ni Boasi náà dé láti Bẹtilẹhẹmu. Ó kí àwọn tí wọn ń kórè ọkà, ó ní, “Kí OLUWA wà pẹlu yín.” Àwọn náà dáhùn pé, “Kí OLUWA bukun ọ.”


Gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà ní ẹnu ọ̀nà ibodè ati àwọn àgbààgbà náà dáhùn pé, “Àwa ni ẹlẹ́rìí, kí OLUWA kí ó ṣe obinrin tí ń bọ̀ wá di aya rẹ bíi Rakẹli ati Lea, tí wọ́n bí ọpọlọpọ ọmọ fún Jakọbu. Yóo dára fún ọ ní Efurata, o óo sì di olókìkí ní Bẹtilẹhẹmu.


Àwọn obinrin àdúgbò bá sọ ọmọ náà ní Obedi, wọ́n ń sọ káàkiri pé, “A bí ọmọkunrin kan fún Naomi.” Obedi yìí ni baba Jese tíí ṣe baba Dafidi.


OLUWA wí fún Samuẹli pé, “Ìgbà wo ni o fẹ́ káàánú lórí Saulu dà? Ṣebí o mọ̀ pé mo ti kọ̀ ọ́ lọ́ba lórí Israẹli. Rọ òróró kún inú ìwo rẹ kí o lọ sọ́dọ̀ Jese ará Bẹtilẹhẹmu, mo ti yan ọba kan fún ara mi ninu àwọn ọmọ rẹ̀.”


Samuẹli ṣe bí OLUWA ti pàṣẹ fún un, ó lọ sí Bẹtilẹhẹmu. Gbígbọ̀n ni àwọn àgbààgbà ìlú bẹ̀rẹ̀ sí gbọ̀n bí wọ́n ti ń lọ pàdé rẹ̀. Wọ́n bi í pé, “Ṣé alaafia ni?”


Ọmọ Jese ni Dafidi, ará Efurati ní Bẹtilẹhẹmu ti Juda; Ọmọkunrin mẹjọ ni Jese bí, ó sì ti di arúgbó nígbà tí Saulu jọba.


Saulu bi í léèrè pé, “Ọmọ, ta ni baba rẹ?” Dafidi dáhùn pé, “Ọmọ Jese ni mí, iranṣẹ rẹ, tí ń gbé Bẹtilẹhẹmu.”


Bí baba rẹ bá bèèrè mi, sọ fún un pé mo ti gbààyè lọ́wọ́ rẹ láti lọ sí ìlú mi, ní Bẹtilẹhẹmu, nítorí pé àkókò yìí jẹ́ àkókò fún àjọ̀dún ẹbọ ọdọọdún ìdílé wa.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan