Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 2:12 - Yoruba Bible

12 Àmì tí ẹ óo fi mọ̀ ọ́n nìyí: ẹ óo rí ọmọ-ọwọ́ náà tí wọ́n fi ọ̀já wé, tí wọ́n tẹ́ sí ibùjẹ ẹran.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

12 Eyi ni yio si ṣe àmi fun nyin; ẹnyin ó ri ọmọ-ọwọ ti a fi ọja wé, o dubulẹ ni ibujẹ ẹran.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

12 Èyí ni yóò sì ṣe ààmì fún yín; ẹ̀yin yóò rí ọmọ ọwọ́ tí a fi ọ̀já wé, ó dùbúlẹ̀ ní ibùjẹ ẹran.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 2:12
11 Iomraidhean Croise  

Nígbà náà ni Aisaya sọ fún Hesekaya ọba pé, “Ohun tí yóo jẹ́ àmì fún ọ nípa àwọn ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ nìyí. Ní ọdún yìí ati ọdún tí ń bọ̀, ẹ óo jẹ àjàrà tí ó lalẹ̀ hù, ṣugbọn ní ọdún tí ó tẹ̀lé e, ẹ óo le gbin ohun ọ̀gbìn yín, ẹ óo sì kórè rẹ̀, ẹ óo gbin ọgbà àjàrà, ẹ óo sì jẹ èso àjàrà rẹ̀.


Hesekaya ọba bèèrè pé, “Kí ni yóo jẹ́ àmì pé OLUWA yóo wò mí sàn, ati pé n óo lọ sí ilé OLUWA ní ọjọ́ kẹta?”


Ṣugbọn kòkòrò lásán ni mí, n kì í ṣe eniyan; ayé kẹ́gàn mi, gbogbo eniyan sì ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà.


Ọlọrun bá dá a lóhùn pé, “N óo wà pẹlu rẹ, ohun tí yóo sì jẹ́ àmì fún ọ, pé èmi ni mo rán ọ ni pé, nígbà tí o bá ti kó àwọn eniyan náà kúrò ní Ijipti, ẹ óo sin Ọlọrun ní orí òkè yìí.”


“Bèèrè àmì tí ó bá wù ọ́ lọ́wọ́ OLUWA Ọlọrun rẹ–ìbáà jìn bí isà òkú, tabi kí ó ga bí ojú ọ̀run.”


Nítorí náà, OLUWA fúnrarẹ̀ yóo fun yín ní àmì kan. Ẹ gbọ́! Ọlọ́mọge kan yóo lóyún yóo sì bí ọmọkunrin kan, yóo pe orúkọ rẹ̀ ní Imanuẹli.


Lójijì ọpọlọpọ àwọn ogun ọ̀run yọ pẹlu angẹli náà, wọ́n ń yin Ọlọrun pé,


Ó bá bí àkọ́bí rẹ̀ ọmọkunrin, ó fi ọ̀já wé e, ó tẹ́ ẹ sí ibùjẹ ẹran, nítorí kò sí àyè fún wọn ninu ilé èrò.


Ní ọjọ́ kan náà ni àwọn ọmọ rẹ mejeeji, Hofini ati Finehasi, yóo kú. Èyí ni yóo jẹ́ àmì fún ọ pé gbogbo ohun tí mo sọ ni yóo ṣẹ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan