Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 2:10 - Yoruba Bible

10 Ṣugbọn angẹli náà wí fún wọn pé, “Ẹ má bẹ̀rù mọ́, nítorí mo mú ìròyìn ayọ̀ ńlá fun yín wá, ayọ̀ tí yóo jẹ́ ti gbogbo eniyan.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

10 Angẹli na si wi fun wọn pe, Má bẹ̀ru: sawò o, mo mu ihinrere ayọ̀ nla fun nyin wá, ti yio ṣe ti enia gbogbo.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

10 Angẹli náà sì wí fún wọn pé, Má bẹ̀rù: sá wò ó, mo mú ìhìnrere ayọ̀ ńlá fún yín wá, tí yóò ṣe ti ènìyàn gbogbo.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 2:10
30 Iomraidhean Croise  

N óo súre fún àwọn tí wọ́n bá súre fún ọ, bí ẹnikẹ́ni bá sì fi ọ́ bú, n óo fi òun náà bú. Nípasẹ̀ rẹ ni n óo bukun gbogbo ìdílé ayé.”


Gun orí òkè gíga lọ, ìwọ Sioni, kí o máa kéde ìyìn rere. Gbé ohùn rẹ sókè pẹlu agbára Jerusalẹmu, ìwọ tí ò ń kéde ìyìn rere ké sókè má ṣe bẹ̀rù; sọ fún àwọn ìlú Juda pé, “Ẹ wo Ọlọrun yín.”


Èmi OLUWA ni mo ti kọ́kọ́ sọ fún Sioni, tí mo sì ròyìn ayọ̀ náà fún Jerusalẹmu.


OLUWA ní nǹkan kékeré ni kí n jẹ́ iranṣẹ òun, láti gbé àwọn ẹ̀yà Jakọbu dìde, ati láti kó àwọn ọmọ Israẹli tí ó kù jọ. Ó ní òun óo fi mí ṣe ìmọ́lẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè kí ìgbàlà òun lè dé òpin ayé.


OLUWA yóo lo agbára mímọ́ rẹ̀, lójú àwọn orílẹ̀-èdè, gbogbo eniyan, títí dé òpin ayé, yóo sì rí ìgbàlà Ọlọrun wa.


Ẹsẹ̀ ẹni tí ń mú ìyìn rere bọ̀ ti dára tó lórí òkè, ẹni tí ń kéde alaafia, tí ń mú ìyìn rere bọ̀, tí sì ń kéde ìgbàlà, tí ń wí fún Sioni pé, “Ọlọrun rẹ jọba.”


Ẹ̀mí OLUWA, Ọlọrun tí bà lé mi, nítorí ó ti fi àmì òróró yàn mí, láti mú ìròyìn ayọ̀ wá fún àwọn tí a ni lára. Ó rán mi pé kí n máa tu àwọn tí ó ní ìbànújẹ́ ninu, kí n máa kéde ìdásílẹ̀ fún àwọn tí ó wà ní ìgbèkùn, kí n sì máa ṣí ìlẹ̀kùn ọgbà ẹ̀wọ̀n sílẹ̀ fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n.


Ó ní, “Ìwọ tí Ọlọrun fẹ́ràn, má bẹ̀rù, alaafia ni, dá ara yá, kí o sì ṣe ọkàn gírí.” Nígbà tí ó bá mi sọ̀rọ̀ tán, mo tún lágbára sí i; mo bá dáhùn pé, “olúwa mi, máa sọ ọ̀rọ̀ rẹ lọ, nítorí ìwọ ni ó fún mi lágbára sí i.”


Ẹ máa yọ̀, ẹ̀yin ará Sioni! Ẹ hó ìhó ayọ̀, ẹ̀yin ará Jerusalẹmu! Wò ó! Ọba yín ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ yín; ajagun-ṣẹ́gun ni, sibẹsibẹ ó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ó sì gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, kódà, ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni ó gùn.


Lẹsẹkẹsẹ Jesu sọ fún wọn pé, “Ẹ ṣe ara gírí. Èmi ni. Ẹ má bẹ̀rù!”


Jesu wá sọ́dọ̀ wọn, ó sọ fún wọn pé, “A ti fún mi ní gbogbo àṣẹ ní ọ̀run ati ní ayé.


Angẹli náà sọ fún àwọn obinrin náà pé, “Ẹ má bẹ̀rù. Mo mọ̀ pé Jesu tí wọ́n kàn mọ́ agbelebu ni ẹ̀ ń wá.


Ó ń wí pé, “Àkókò tó; ìjọba Ọlọrun súnmọ́ ìtòsí. Ẹ ronupiwada, kí ẹ gba ìyìn rere gbọ́.”


Ó bá sọ fún wọn pé, “Ẹ lọ sí gbogbo ayé, kí ẹ máa waasu ìyìn rere fún gbogbo ẹ̀dá.


Ṣugbọn angẹli náà sọ fún un pé, “Má bẹ̀rù, Sakaraya, nítorí pé adura rẹ ti gbà. Elisabẹti iyawo rẹ yóo bí ọmọkunrin kan fún ọ, o óo pe orúkọ rẹ̀ ní Johanu.


Angẹli náà dá a lóhùn pé, “Geburẹli ni orúkọ mi, èmi ni mo máa ń dúró níwájú Ọlọrun. Ọlọrun ló rán mi láti bá ọ sọ̀rọ̀, ati láti sọ nǹkan ayọ̀ yìí fún ọ.


Angẹli náà sọ fún un pé, “Má bẹ̀rù, Maria, nítorí o ti bá ojurere Ọlọrun pàdé.


Nítorí a bí Olùgbàlà fun yín lónìí, ní ìlú Dafidi, tíí ṣe Oluwa ati Mesaya.


Ati pé ní orúkọ rẹ̀, kí á máa waasu ìrònúpìwàdà ati ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ohun tí ó bẹ̀rẹ̀ láti Jerusalẹmu.


Lẹ́yìn èyí, Jesu ń rìn káàkiri láti ìlú dé ìlú, ati láti abúlé dé abúlé. Ó ń waasu ìyìn rere ìjọba Ọlọrun. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila ń bá a kiri.


A wá mú ìyìn rere wá fun yín pé ìlérí tí Ọlọrun ṣe fún àwọn baba wa ti ṣẹ, fún àwọn ọmọ wa, nígbà tí ó jí Jesu dìde, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ ninu Orin Dafidi keji pé, ‘Ọmọ mi ni ọ́, lónìí yìí ni mo bí ọ.’


Báwo ni àwọn kan yóo ṣe lọ kéde rẹ̀ láìjẹ́ pé a bá rán wọn lọ? Ó wà ninu Ìwé Mímọ́ pé, “Àwọn tí ó mú ìyìn rere wá mà mọ̀ ọ́n rìn o!”


Nítorí èmi tí mo kéré jùlọ ninu gbogbo àwọn onigbagbọ ni Ọlọrun fi oore-ọ̀fẹ́ yìí fún, pé kí n máa waasu fún àwọn tí kì í ṣe Juu nípa àwámárìídìí ọrọ̀ Kristi.


tí ẹ bá dúró ninu igbagbọ, tí ẹ fi ẹsẹ̀ múlẹ̀, tí ẹ dúró gbọningbọnin, tí ẹ kò kúrò ninu ìrètí ìyìn rere tí ẹ ti gbọ́, tí èmi Paulu jẹ́ iranṣẹ rẹ̀, tí a ti waasu rẹ̀ fún gbogbo ẹ̀dá ayé.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan