Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 17:3 - Yoruba Bible

3 Ẹ ṣọ́ra yín! “Bí arakunrin rẹ bá ṣẹ̀ ọ́, bá a wí; bí ó bá ronupiwada, dáríjì í.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 Ẹ mã kiyesara nyin: bi arakunrin rẹ ba ṣẹ̀, ba a wi; bi o ba si ronupiwada, dari jì i.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Ẹ máa kíyèsára yín. “Bí arákùnrin rẹ bá ṣẹ̀, bá a wí; bí ó bá sì ronúpìwàdà, dáríjì ín.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 17:3
18 Iomraidhean Croise  

N ò kọ̀ kí ẹni rere bá mi wí, n ò kọ̀ kí ó nà mí; kí ó ṣá ti fi ìfẹ́ bá mi wí. Ṣugbọn má jẹ́ kí eniyan burúkú tilẹ̀ ta òróró sí mi lórí, nítorí pé nígbàkúùgbà ni mò ń fi adura tako ìwà ibi wọn.


Ẹ ṣọ́ra gidigidi, kí ẹ rí i pé ẹ kò bá àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ tí ẹ̀ ń lọ dá majẹmu kankan, kí wọn má baà dàbí tàkúté tí a dẹ sí ààrin yín.


Ìbáwí a máa dun ọlọ́gbọ́n ju kí wọ́n nà òmùgọ̀ ní ọgọrun-un pàṣán lọ.


Ìbáwí ní gbangba sàn ju ìfẹ́ kọ̀rọ̀ lọ.


Má ṣe bá oníyẹ̀yẹ́ eniyan wí, kí ó má baà kórìíra rẹ, bá ọlọ́gbọ́n wí, yóo sì fẹ́ràn rẹ.


“Ẹ kò gbọdọ̀ di arakunrin yín sinu, ṣugbọn ẹ gbọdọ̀ máa sọ àsọyé pẹlu aládùúgbò yín, kí ẹ má baà gbẹ̀ṣẹ̀ nítorí tirẹ̀.


Nígbà náà ni Peteru wá sọ́dọ̀ Jesu, ó bi í pé, “Oluwa, ìgbà mélòó ni arakunrin mi óo ṣẹ̀ mí tí n óo dáríjì í? Ṣé kí ó tó ìgbà meje?”


“Ẹ ṣọ́ra yín, kí ẹ má jẹ́ kí ayẹyẹ, tabi ìfiṣòfò, tabi ọtí mímu, ati àníyàn ayé gba ọkàn yín, tí ó fi jẹ́ pé lójijì ni ọjọ́ náà yóo dé ba yín bí ìgbà tí tàkúté bá mú ẹran.


Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra bí ẹ ti ń hùwà. Ẹ má ṣe hùwà bí ẹni tí kò gbọ́n, ṣugbọn ẹ hùwà bí ọlọ́gbọ́n.


“Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra gidigidi, níwọ̀n ìgbà tí ẹ kò rí ìrísí OLUWA ní ọjọ́ tí ó ba yín sọ̀rọ̀ láàrin iná ní Horebu,


Ẹ ṣọ́ra gidigidi, ẹ má gbàgbé majẹmu tí OLUWA Ọlọrun yín ba yín dá, ẹ má sì yá èrekére fún ara yín, ní àwòrán ohunkohun, nítorí pé, OLUWA Ọlọrun yín lòdì sí i.


Ẹ ṣọ́ra gidigidi, kí ẹ sì ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, kí ẹ má baà gbàgbé àwọn ohun tí ẹ ti fi ojú ara yín rí, kí iyè yín má baà fò wọ́n ní gbogbo ọjọ́ ayé yín. Ẹ máa pa á nítàn fún àwọn ọmọ yín ati àwọn ọmọ ọmọ yín,


Ẹ ṣọ́ra kí ẹnikẹ́ni ninu yín má fà sẹ́yìn kúrò ninu oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun. Ẹ ṣọ́ra kí ẹnikẹ́ni má ṣe dàbí igi kíkorò, tí yóo dàgbà tán tí yóo wá fi ìkorò tirẹ̀ kó ìdààmú bá ọpọlọpọ ninu yín.


Ẹ̀yin ará mi, bí ẹnikẹ́ni ninu yín bá ṣìnà kúrò ninu òtítọ́, tí ẹnìkan bá tọ́ ọ sọ́nà,


Ẹ ṣọ́ra kí ẹ má baà pa iṣẹ́ tí ẹ ti ṣe run, kí ẹ lè gba èrè kíkún.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan