Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 16:4 - Yoruba Bible

4 Mo mọ ohun tí n óo ṣe, kí àwọn eniyan lè gbà mí sinu ilé wọn nígbà tí wọ́n bá gba iṣẹ́ lọ́wọ́ mi.’

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

4 Mo mọ̀ eyiti emi o ṣe, nigbati a ba mu mi kuro nibi iṣẹ iriju, ki nwọn ki o le gbà mi sinu ile wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Mo mọ èyí tí èmi yóò ṣe, nígbà tí a bá mú mi kúrò níbi iṣẹ́ ìríjú, kí àwọn ènìyàn le gbà mí sínú ilé wọn.’

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 16:4
6 Iomraidhean Croise  

kí n má baà yó tán, kí n sẹ́ ọ, kí n wí pé, “Ta ni ń jẹ́ OLUWA?” Má sì jẹ́ kí n tòṣì, kí n má baà jalè, kí n sì kó ẹ̀gbin bá orúkọ Ọlọrun.


OLUWA ní, “Nítorí pé àwọn eniyan mi gọ̀, wọn kò mọ̀ mí. Òmùgọ̀ ọmọ ni wọ́n; wọn kò ní òye. Ọgbọ́n àtiṣe ibi kún inú wọn: ṣugbọn wọn kò mọ rere ṣe.”


Ọmọ-ọ̀dọ̀ náà wá rò ninu ara rẹ̀ pé, ‘Kí ni n óo ṣe o, nítorí ọ̀gá mi yóo dá mi dúró lẹ́nu iṣẹ́. Èmi nìyí, n kò lè roko. Ojú sì ń tì mí láti máa ṣagbe.


“Ó bá pe ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn tí ó jẹ ọ̀gá rẹ̀ ní gbèsè. Ó bi ekinni pé, ‘Èló ni o jẹ ọ̀gá mi?’


“Ní tèmi, mò ń sọ fun yín, fún anfaani ara yín, ẹ fi ọrọ̀ ayé yìí wá ọ̀rẹ́ fún ara yín, tí ó fi jẹ́ pé nígbà tí owó kò bá sí mọ́, kí wọn lè gbà yín sí inú ibùgbé tí yóo wà títí lae.


Èyí kì í ṣe ọgbọ́n tí ó wá láti òkè, ọgbọ́n ayé ni, gẹ́gẹ́ bíi ti ẹran-ara, ati ti ẹ̀mí burúkú.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan