Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 16:3 - Yoruba Bible

3 Ọmọ-ọ̀dọ̀ náà wá rò ninu ara rẹ̀ pé, ‘Kí ni n óo ṣe o, nítorí ọ̀gá mi yóo dá mi dúró lẹ́nu iṣẹ́. Èmi nìyí, n kò lè roko. Ojú sì ń tì mí láti máa ṣagbe.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 Iriju na si wi ninu ara rẹ̀ pe, Ewo li emi o ṣe? nitoriti Oluwa mi gbà iṣẹ iriju lọwọ mi: emi kò le wàlẹ; lati ṣagbe oju ntì mi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 “Ìríjú náà sì wí nínú ara rẹ̀ pé, ‘Èwo ni èmi ó ṣe? Nítorí tí olúwa mi gba iṣẹ́ ìríjú lọ́wọ́ mi: èmi kò le ṣiṣẹ́ oko, bẹ́ẹ̀ ni ojú ń tì mí láti ṣagbe.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 16:3
26 Iomraidhean Croise  

Bí Hamani tí ń wọlé ni ọba bi í pé, “Kí ló yẹ kí á ṣe fún ẹni tí inú ọba dùn sí?” Hamani rò ó ninu ara rẹ̀ pé, ta ni ọba ìbá tún dá lọ́lá bíkòṣe òun.


Ọkàn ọ̀lẹ ń fẹ́ nǹkan, ṣugbọn kò ní rí i, ṣugbọn ẹni tí ń fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ yóo ní ọpọlọpọ nǹkan.


Ẹ̀gún kún bo ọ̀nà ọ̀lẹ, ṣugbọn ọ̀nà olódodo dàbí òpópó tí ń dán.


Ẹni tí ń ṣe ìmẹ́lẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀, ẹgbẹ́ ni òun ati ẹni tí ń ba nǹkan jẹ́.


Ìwà ọ̀lẹ a máa múni sùn fọnfọn, ebi níí sìí pa alápá-má-ṣiṣẹ́.


Ọ̀lẹ kì í dáko ní àkókò, nítorí náà, nígbà ìkórè, kò ní rí nǹkankan kó jọ.


Bí eniyan bá kẹ́ ẹrú ní àkẹ́jù, yóo ya ìyàkuyà níkẹyìn.


Kí ni ẹ óo ṣe lọ́jọ́ ìjìyà yín tí ìparun bá dé láti òkèèrè? Ta ni ẹ óo sá tọ̀ lọ fún ìrànlọ́wọ́? Níbo ni ẹ óo kó ọrọ̀ yín sí?


Àwọn wolii ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké, àwọn alufaa ń sọ ọ̀rọ̀ èké àwọn wolii di òfin, àwọn eniyan mi sì fẹ́ ẹ bẹ́ẹ̀. Ṣugbọn kí ni wọ́n óo ṣe nígbà tí òpin bá dé?”


Kí ni wọn óo ṣe ní ọjọ́ àjọ̀dún tí a yà sọ́tọ̀, kí ni wọn óo ṣe ní ọjọ́ àsè OLUWA?


“Nígbà tí ọjọ́ rọ̀, ẹni tí ó ni ọgbà àjàrà náà sọ fún iranṣẹ rẹ̀ pé, ‘Pe àwọn òṣìṣẹ́, kí o fún wọn ní owó wọn, bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn tí ó dé gbẹ̀yìn, títí dé ọ̀dọ̀ àwọn tí ó kọ́kọ́ dé.’


Wọn dé Jẹriko. Bí Jesu pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ati ogunlọ́gọ̀ eniyan ti ń jáde kúrò ní Jẹriko, Batimiu afọ́jú, ọmọ Timiu, jókòó lẹ́bàá ọ̀nà, ó ń ṣagbe.


Ó wá ń rò ninu ọkàn rẹ̀ pé, ‘Kí ni ǹ bá ṣe o, nítorí n kò rí ibi kó ìkórè oko mi pamọ́ sí?’


Ọ̀gá rẹ̀ bá pè é, ó sọ fún un pé, ‘Irú ìròyìn wo ni mò ń gbọ́ nípa rẹ yìí? Ṣírò iṣẹ́ rẹ bí ọmọ-ọ̀dọ̀, nítorí n óo dá ọ dúró lẹ́nu iṣẹ́.’


Talaka kan wà tí ó ń jẹ́ Lasaru, tíí máa ń jókòó lẹ́nu ọ̀nà ilé ọlọ́rọ̀ yìí. Gbogbo ara Lasaru jẹ́ kìkì egbò.


“Nígbà tí ó yá, talaka yìí kú, àwọn angẹli bá gbé e lọ sọ́dọ̀ Abrahamu. Olówó náà kú, a sì sin ín.


Mo mọ ohun tí n óo ṣe, kí àwọn eniyan lè gbà mí sinu ilé wọn nígbà tí wọ́n bá gba iṣẹ́ lọ́wọ́ mi.’


Ọjọ́ ń gorí ọjọ́, sibẹ adájọ́ yìí kò fẹ́ ṣe nǹkankan nípa ọ̀rọ̀ náà. Nígbà tí ó pẹ́, ó wá bá ara rẹ̀ sọ pé, ‘Bí n kò tilẹ̀ bìkítà fún ẹnikẹ́ni, ìbáà ṣe Ọlọrun tabi eniyan,


Nígbà tí àwọn aládùúgbò rẹ̀ ati àwọn tí wọn máa ń rí i tẹ́lẹ̀ tí ó máa ń ṣagbe, rí i, wọ́n ń bi ara wọn pé, “Ǹjẹ́ ọkunrin yìí kọ́ ni ó ti máa ń jókòó, tí ó máa ń ṣagbe rí?”


Ọkunrin kan wà tí wọn máa ń gbé wá sibẹ, tí ó yarọ láti inú ìyá rẹ̀ wá. Lojoojumọ, wọn á máa gbé e wá sí ẹnu ọ̀nà Tẹmpili tí à ń pè ní “Ẹnu Ọ̀nà Dáradára,” kí ó lè máa ṣagbe lọ́dọ̀ àwọn tí ń wọ inú Tẹmpili lọ.


Dìde nisinsinyii, kí o wọ inú ìlú lọ. A óo sọ ohun tí o níláti ṣe fún ọ.”


Nítorí a gbọ́ pé àwọn kan ninu yín ń rìn ségesège, wọn kì í ṣiṣẹ́ rárá, ẹsẹ̀ ni wọ́n fi í máa wọ́lẹ̀ kiri.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan