Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 16:2 - Yoruba Bible

2 Ọ̀gá rẹ̀ bá pè é, ó sọ fún un pé, ‘Irú ìròyìn wo ni mò ń gbọ́ nípa rẹ yìí? Ṣírò iṣẹ́ rẹ bí ọmọ-ọ̀dọ̀, nítorí n óo dá ọ dúró lẹ́nu iṣẹ́.’

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

2 Nigbati o si pè e, o wi fun u pe, Ẽṣe ti emi fi ngbọ́ eyi si ọ? siro iṣẹ iriju rẹ; nitori iwọ ko le ṣe iriju mọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Nígbà tí ó sì pè é, ó wí fún un pé, ‘Èéṣe tí èmi fi ń gbọ́ èyí sí ọ? Ṣírò iṣẹ́ ìríjú rẹ; nítorí ìwọ kò lè ṣe ìríjú mi mọ́.’

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 16:2
23 Iomraidhean Croise  

Nítorí Ọlọrun yóo mú gbogbo nǹkan tí eniyan bá ṣe wá sí ìdájọ́, ati gbogbo nǹkan àṣírí, ìbáà ṣe rere tabi burúkú.


“Ṣugbọn mo sọ fun yín pé gbogbo ọ̀rọ̀ tí eniyan bá ń sọ láì ronú ni yóo dáhùn fún ní ọjọ́ ìdájọ́.


“Nígbà tí ọjọ́ rọ̀, ẹni tí ó ni ọgbà àjàrà náà sọ fún iranṣẹ rẹ̀ pé, ‘Pe àwọn òṣìṣẹ́, kí o fún wọn ní owó wọn, bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn tí ó dé gbẹ̀yìn, títí dé ọ̀dọ̀ àwọn tí ó kọ́kọ́ dé.’


Ṣugbọn Ọlọrun wí fún un pé, ‘Ìwọ aṣiwèrè yìí! Ní alẹ́ yìí ni a óo gba ẹ̀mí rẹ pada lọ́wọ́ rẹ. Ta ni yóo wá jogún gbogbo ohun tí o kó jọ wọnyi?’


Oluwa sọ pé, “Ta ni olóòótọ́ ati ọlọ́gbọ́n ọmọ-ọ̀dọ̀, ẹni tí oluwa rẹ̀ fi ṣe olórí àwọn iranṣẹ ilé rẹ̀ pé kí ó máa fún wọn ní oúnjẹ lásìkò.


Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn pé, “Ọkunrin ọlọ́rọ̀ kan wà tí ó ní ọmọ-ọ̀dọ̀ kan. Wọ́n fi ẹ̀sùn kan ọmọ-ọ̀dọ̀ yìí pé ó ń fi nǹkan ọ̀gá rẹ̀ ṣòfò.


Ọmọ-ọ̀dọ̀ náà wá rò ninu ara rẹ̀ pé, ‘Kí ni n óo ṣe o, nítorí ọ̀gá mi yóo dá mi dúró lẹ́nu iṣẹ́. Èmi nìyí, n kò lè roko. Ojú sì ń tì mí láti máa ṣagbe.


Nítorí náà, olukuluku wa ni yóo sọ ti ẹnu ara rẹ̀ níwájú Ọlọrun.


Nítorí pé ninu ìròyìn tí àwọn ará Kiloe mú wá, ó hàn sí mi gbangba pé ìjà wà láàrin yín.


Ohun tí à ń retí lọ́dọ̀ ìríjú ni pé kí ó jẹ́ olóòótọ́.


Nítorí náà, kí ẹnikẹ́ni má ṣe ìdájọ́ kí àkókò rẹ̀ tó tó, nígbà tí Oluwa yóo dé, tí yóo tan ìmọ́lẹ̀ sí ohun gbogbo tí ó fara pamọ́ sinu òkùnkùn, tí yóo mú kí gbogbo èrò ọkàn eniyan farahàn kedere. Nígbà náà ni olukuluku yóo gba iyìn tí ó yẹ láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun.


Nítorí gbogbo wa níláti lọ siwaju Kristi bí a ti rí, láti lọ jẹ́ ẹjọ́. Níbẹ̀ ni olukuluku yóo ti gba ohun tí ó tọ́ sí i fún oríṣìíríṣìí ìwà tí ó ti hù nígbà tí ó wà ninu ara, ìbáà ṣe rere, ìbáà ṣe burúkú.


Má ṣe àìnáání ẹ̀bùn tí Ẹ̀mí Mímọ́ fún ọ nípa àsọtẹ́lẹ̀ nígbà tí àwọn àgbà ìjọ gbé ọwọ́ lé ọ lórí.


Àwọn kan wà tí ẹ̀ṣẹ̀ wọn hàn sí gbogbo eniyan, àwọn adájọ́ ti mọ̀ wọ́n kí wọ́n tó mú wọn dé kọ́ọ̀tù. Ṣugbọn ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ẹlòmíràn a máa pẹ́ kí ó tó hàn sóde.


Olukuluku yín ní ẹ̀bùn tirẹ̀. Ẹ máa lo ẹ̀bùn yín fún ire ọmọnikeji yín, gẹ́gẹ́ bí ìríjú oríṣìíríṣìí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun.


Ṣugbọn wọn óo dáhùn fún ìwà wọn níwájú ẹni tí ó ṣetán láti ṣe ìdájọ́ alààyè ati òkú.


Mo rí òkú àwọn ọlọ́lá ati ti àwọn mẹ̀kúnnù, tí wọ́n dúró níwájú ìtẹ́ náà. Àwọn ìwé àkọsílẹ̀ wà ní ṣíṣí. Ìwé mìíràn tún wà ní ṣíṣí, tí orúkọ àwọn alààyè wà ninu rẹ̀. A wá bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìdájọ́ àwọn òkú gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn tí ó wà ninu àwọn ìwé àkọsílẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan