Luku 16:1 - Yoruba Bible1 Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn pé, “Ọkunrin ọlọ́rọ̀ kan wà tí ó ní ọmọ-ọ̀dọ̀ kan. Wọ́n fi ẹ̀sùn kan ọmọ-ọ̀dọ̀ yìí pé ó ń fi nǹkan ọ̀gá rẹ̀ ṣòfò. Faic an caibideilBibeli Mimọ1 O si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pẹlu pe, Ọkunrin ọlọrọ̀ kan wà, ti o ni iriju kan; on na ni nwọn fi sùn u pe, o ti nfi ohun-ini rẹ̀ ṣòfo. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní1 Ó sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pẹ̀lú pé, “Ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan wà, tí ó ní ìríjú kan; òun náà ni wọ́n fi sùn ún pé, ó ti ń fi ohun ìní rẹ̀ ṣòfò. Faic an caibideil |
Dafidi ọba pe gbogbo àwọn olórí ní ilẹ̀ Israẹli jọ sí Jerusalẹmu, àwọn olórí láàrin àwọn ẹ̀yà Israẹli, àwọn olórí àwọn ìpín tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ fún ọba, àwọn ọ̀gágun ẹgbẹẹgbẹrun ọmọ ogun, ati ọgọọgọrun-un ọmọ ogun, gbogbo àwọn tí wọ́n jẹ́ alabojuto ohun ìní ati ẹran ọ̀sìn ọba, àwọn tí wọ́n ń tọ́jú àwọn ọmọ ọba, àwọn tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ ní ààfin, àwọn eniyan pataki pataki ati àwọn akọni ọmọ ogun, gbogbo wọn péjọ sí Jerusalẹmu.