N óo láyọ̀ ninu Jerusalẹmu, inú mi óo sì máa dùn sí àwọn eniyan mi. A kò ní gbọ́ igbe ẹkún ninu rẹ̀ mọ́, ẹnikẹ́ni kò sì ní sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn ninu rẹ̀ mọ́.
Ẹ lọ kọ́ ìtumọ̀ gbolohun yìí: Ọlọrun sọ pé, ‘Àánú ṣíṣe ni mo fẹ́, kì í ṣe ẹbọ rírú.’ Nítorí náà kì í ṣe àwọn olódodo ni mo wá pè, bíkòṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.”
“Bí ọkunrin kan bá ní ọgọrun-un aguntan tí ọ̀kan sọnù ninu wọn, ṣé kò ní fi mọkandinlọgọrun-un yòókù sílẹ̀ ní pápá, kí ó wá èyí tí ó sọnù lọ títí yóo fi rí i?
Jesu tún bi í lẹẹkeji pé, “Simoni ọmọ Johanu, ǹjẹ́ o fẹ́ràn mi?” Ó tún dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni Oluwa, o mọ̀ pé mo fẹ́ràn rẹ.” Jesu wí fún un pé, “Máa tọ́jú àwọn aguntan mi.”
Nígbà tí wọ́n gbọ́, wọ́n fi ògo fún Ọlọrun. Àwọn náà wá sọ fún un pé, “Wò ó ná, arakunrin, ṣé o mọ̀ pé ẹgbẹẹgbẹrun ni àwọn Juu tí ó gba Jesu gbọ́, tí gbogbo wọn sì ní ìtara sí Òfin Mose.