Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 14:7 - Yoruba Bible

7 Nígbà tí Jesu ṣe akiyesi bí àwọn tí a pè sí ibi àsè ti ń yan ipò ọlá, ó wá pa òwe kan fún wọn. Ó ní,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

7 O si pa owe kan fun awọn ti a pè wá jẹun, nigbati o wò bi nwọn ti nyàn ipò ọlá; o si wi fun wọn pe,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Ó sì pa òwe kan fún àwọn tí ó pè é wá jẹun, nígbà tí ó ṣàkíyèsí bí wọ́n ti ń yan ipò ọlá; ó sì wí fún wọn pé:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 14:7
12 Iomraidhean Croise  

nítorí ó sàn kí ó wí fún ọ pé, “Máa bọ̀ lókè níhìn-ín”, jù pé kí ó rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ níwájú ọlọ́lá kan lọ.


Ọgbọ́n ń pe eniyan, òye ń pariwo.


“Ìwọ ọmọ eniyan, pa àlọ́ kan kí o sì fi òwe bá àwọn ọmọ Israẹli sọ̀rọ̀.


Jesu sọ gbogbo nǹkan wọnyi fún àwọn eniyan ní òwe. Kò sọ ohunkohun fún wọn láì lo òwe;


Wọ́n fẹ́ràn ìjókòó ọlá níbi àsè. Wọ́n fẹ́ràn àga iwájú ní ilé ìpàdé.


“Ẹ gbé! Ẹ̀yin Farisi. Nítorí ẹ fẹ́ràn ìjókòó iwájú ninu ilé ìpàdé. Ẹ tún fẹ́ràn kí eniyan máa ki yín láàrin ọjà.


“Ẹ ṣọ́ra lọ́dọ̀ àwọn amòfin tí wọ́n fẹ́ máa wọ agbádá ńlá. Wọ́n tún gbádùn kí eniyan máa kí wọn ní ààrin ọjà. Wọ́n fẹ́ràn láti jókòó níwájú ninu ilé ìpàdé ati láti jókòó ní ipò ọlá níbi àsè.


Ẹ má ṣe ohunkohun pẹlu ẹ̀mí àṣehàn tabi láti gba ìyìn eniyan, ṣugbọn pẹlu ọkàn ìrẹ̀lẹ̀, ẹ máa fi ẹnìkejì yín ṣiwaju ara yín.


Mo kọ ìwé kan sí ìjọ ṣugbọn Diotirefe tí ó fẹ́ ipò aṣiwaju láàrin ìjọ kò gba ohun tí mo sọ.


Samsoni bá sọ fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí n pa àlọ́ kan fun yín, bí ẹ bá lè túmọ̀ àlọ́ náà láàrin ọjọ́ meje tí a ó fi se àsè igbeyawo yìí, n óo fun yín ní ọgbọ̀n ẹ̀wù funfun ati ọgbọ̀n aṣọ àríyá.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan