6 Wọn kò sì lè dá a lóhùn.
6 Nwọn kò si le da a li ohùn mọ́ si nkan wọnyi.
6 Wọn kò sì lè dá a lóhùn mọ́ sí nǹkan wọ̀nyí.
Kò sí ẹnìkan tí ó lè dá a lóhùn ọ̀rọ̀ yìí. Láti ọjọ́ náà, ẹnikẹ́ni kò ní ìgboyà láti tún bi í ní ohunkohun mọ́.
Nígbà tí ó sọ̀rọ̀ báyìí, ojú ti gbogbo àwọn tí ó takò o. Ńṣe ni inú gbogbo àwọn eniyan dùn nítorí gbogbo ohun ìyanu tí ó ń ṣe.
Wọn kò lè mú ọ̀rọ̀ mọ́ ọn lẹ́nu lójú gbogbo eniyan. Ìdáhùn rẹ̀ yà wọ́n lẹ́nu, wọ́n bá dákẹ́.
Láti ìgbà náà kò tún sí ẹni tí ó láyà láti bi í ní nǹkankan mọ́.
nítorí èmi fúnra mi ni n óo fi ọ̀rọ̀ si yín lẹ́nu, n óo sì fun yín ní ọgbọ́n tí ó fi jẹ́ pé ẹnikẹ́ni ninu gbogbo àwọn tí ó lòdì si yín kò ní lè kò yín lójú, tabi kí wọ́n rí ohun wí si yín.
Ṣugbọn wọn kò lè fèsì sí irú ọgbọ́n ati ẹ̀mí tí ó fi ń sọ̀rọ̀.