Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 13:8 - Yoruba Bible

8 Ṣugbọn olùtọ́jú ọgbà dá a lóhùn pé, ‘Alàgbà, fi í sílẹ̀ ní ọdún yìí, kí n walẹ̀ yí i ká, kí n bu ilẹ̀dú sí i.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

8 O si dahùn o wi fun u pe, Oluwa, jọwọ rẹ̀ li ọdún yi pẹlu, titi emi o fi tú ilẹ idi rẹ̀ yiká, titi emi o si fi bu ilẹdu si i:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 “Ó sì dáhùn ó wí fún un pé, ‘Olúwa, jọ̀wọ́ rẹ̀ ní ọdún yìí pẹ̀lú, títí èmi ó fi tu ilẹ̀ ìdí rẹ̀ yíká, títí èmi ó sì fi bu ìlẹ̀dú sí i:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 13:8
17 Iomraidhean Croise  

Nítorí náà ni ó ṣe wí pé òun yóo pa wọ́n run, bí kì í bá ṣe ti Mose, àyànfẹ́ rẹ̀, tí ó dúró níwájú rẹ̀, tí ó sì ṣìpẹ̀, láti yí ibinu OLUWA pada, kí ó má baà pa wọ́n run.


Ó ní, “Bí inú rẹ bá dùn sí mi nítòótọ́, OLUWA, jọ̀wọ́, máa wà láàrin wa, nígbà tí a bá ń lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé olóríkunkun ni àwọn eniyan náà; dárí ẹ̀ṣẹ̀ ati àìṣedéédé wa jì wá, kí o sì gbà wá gẹ́gẹ́ bí eniyan rẹ.”


OLUWA bá tún sọ fún mi pé, “Mose ati Samuẹli ìbáà wá dúró níwájú mi, ọkàn mi kò lè yọ́ sí àwọn eniyan wọnyi. Lé wọn kúrò níwájú mi, kí wọ́n máa lọ!


Ṣé ibi ni eniyan fi í san rere? Sibẹ wọ́n ti wa kòtò sílẹ̀ fún mi. Ranti bí mo ti dúró níwájú rẹ tí mo sọ ọ̀rọ̀ wọn ní rere, kí o baà lè yí ibinu rẹ pada lórí wọn.


Kí àwọn alufaa, àwọn iranṣẹ Ọlọrun, sọkún láàrin ẹnu ọ̀nà àbáwọlé ati pẹpẹ ìrúbọ. Kí wọ́n wí pé “OLUWA, dá àwọn eniyan rẹ sí, má sì sọ ilẹ̀ rẹ di ohun ẹ̀gàn ati ohun ẹ̀sín láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù. Má jẹ́ kí àwọn eniyan láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù bèèrè pé, ‘Níbo ni Ọlọrun wọn wà?’ ”


Ó wá sọ fún olùtọ́jú ọgbà pé, ‘Ṣé o rí i! Ó di ọdún mẹta tí mo ti ń wá èso lórí igi ọ̀pọ̀tọ́ yìí tí n kò rí. Gé e lulẹ̀. Kí ló dé tí yóo kàn máa gbilẹ̀ lásán?’


Bí ó bá so èso ní ọdún tí ń bọ̀, ó dára. Bí kò bá so èso, gé e.’ ”


Kó wúlò fún oko tabi fún ààtàn mọ́ àfi kí á dà á sóde. Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ràn, kí ó gbọ́!”


Ẹ̀yin ará mi, ìfẹ́ ọkàn mi, ati ẹ̀bẹ̀ mi sí Ọlọrun fún àwọn Juu, àwọn eniyan mi ni pé kí á gbà wọ́n là.


pé bóyá mo lè ti ipa bẹ́ẹ̀ mú àwọn eniyan mi jowú yín, kí n lè gba díẹ̀ ninu wọn là.


Oluwa kò jáfara nípa ìlérí rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn kan ti rò, ṣugbọn ó ń mú sùúrù fun yín ni. Kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni ṣègbé ṣugbọn ó fi ààyè sílẹ̀ kí gbogbo eniyan lè ronupiwada.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan