Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 13:7 - Yoruba Bible

7 Ó wá sọ fún olùtọ́jú ọgbà pé, ‘Ṣé o rí i! Ó di ọdún mẹta tí mo ti ń wá èso lórí igi ọ̀pọ̀tọ́ yìí tí n kò rí. Gé e lulẹ̀. Kí ló dé tí yóo kàn máa gbilẹ̀ lásán?’

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

7 O si wi fun oluṣọgba rẹ̀ pe, Sawõ, lati ọdún mẹta li emi ti nwá iwò eso lori igi ọpọtọ yi, emi ko si ri nkan: ké e lulẹ; ẽṣe ti o fi ngbilẹ lasan pẹlu?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Ó sì wí fún olùṣọ́gbà rẹ̀ pé, ‘Sá à wò ó, láti ọdún mẹ́ta ni èmi ti ń wá í wo èso lórí igi ọ̀pọ̀tọ́ yìí, èmi kò sì rí nǹkan: ké e lulẹ̀; èéṣe tí ó fi ń gbilẹ̀ lásán pẹ̀lú?’

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 13:7
11 Iomraidhean Croise  

Dá mi dá wọn, inú ń bí mi sí wọn gidigidi, píparẹ́ ni n óo sì pa wọ́n rẹ́, ṣugbọn n óo sọ ìwọ di orílẹ̀-èdè ńlá.”


ó kígbe sókè pé, ‘Gé igi náà lulẹ̀, gé àwọn ẹ̀ka rẹ̀ kúrò, gbọn gbogbo ewé ati èso rẹ̀ dànù; kí àwọn ẹranko sá kúrò lábẹ́ rẹ̀, kí àwọn ẹyẹ sì fò kúrò lórí ẹ̀ka rẹ̀.


“Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ náà, tí ẹ bá sì gbin oríṣìíríṣìí igi eléso fún jíjẹ, ẹ ka gbogbo èso tí wọ́n bá so fún ọdún mẹta ti àkọ́kọ́ sí aláìmọ́; èèwọ̀ ni, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́.


Èmi OLUWA yóo pàṣẹ pé kí ibukun mi wà lórí yín ní ọdún kẹfa tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé ilẹ̀ yóo so èso tí yóo to yín jẹ fún ọdún mẹta.


Igikígi tí kò bá so èso rere, gígé ni a óo gé e lulẹ̀, tí a óo sì fi dáná.


Ṣugbọn olùtọ́jú ọgbà dá a lóhùn pé, ‘Alàgbà, fi í sílẹ̀ ní ọdún yìí, kí n walẹ̀ yí i ká, kí n bu ilẹ̀dú sí i.


A sì ti fi àáké lé gbòǹgbò igi báyìí. Nítorí náà, igikígi tí kò bá máa so èso rere ni a óo gé lulẹ̀, tí a óo sì fi dáná.”


Gígé ni yóo gé gbogbo ẹ̀ka ara mi tí kò bá so èso, ṣugbọn yóo re ọwọ́ gbogbo ẹ̀ka tí ó bá ń so èso, kí wọ́n lè mọ́, kí wọ́n sì lè máa so sí i lọpọlọpọ.


Bí ẹnikẹ́ni kò bá gbé inú mi, a óo jù ú sóde bí ẹ̀ka, yóo sì gbẹ; wọn óo mú un, wọn óo sì fi dáná, yóo bá jóná.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan